93 Days | |
---|---|
Adarí | Steve Gukas |
Olùgbékalẹ̀ |
|
Òǹkọ̀wé | Paul S. Rowlston |
Àwọn òṣèré | |
Orin | George Kallis |
Ìyàwòrán sinimá | Yinka Edward |
Olóòtú | Antonio Rui Ribeiro |
Déètì àgbéjáde |
|
Àkókò | 118 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English |
93 Days jẹ́ fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jáde ní ọdún 2016. Ó jé fíìmù ajẹmọ́-ìṣẹ̀lẹ̀-tó-le, èyí tí Steve Gukas darí.[2] Fíìmù náà sọ ìtàn àrùn Ebola tó wáyé ní ọdún 2014 ní Nàìjíríà àti bí àọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ṣe kojú rẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé-ìwòsàn kan ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Lára àwọn òṣèré tó kópa nínú rẹ̀ ni Bimbo Akintola, Danny Glover àti Bimbo Manuel, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Native FilmWorks, Michel Angelo Production àti Bolanle Austen-Peters Production.[3]
Wọ́n fi fíìmù 93 Days yìí sọrí Ameyo Adadevoh, tó jẹ́ oníṣègùn Nàìjíríà kan tó kó ipa rẹpẹtẹ nínú bíborí àrùn Ebola ní Nàìjíríà.
Ní 20 July 2014, Patrick Sawyer, tó jẹ́ ọmọ Liberia tó tan mọ́ ìlú America dé sí ìpínlẹ̀ Èkó, ní Nàìjíríà. Ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbe lọ sí First Consultants Medical Center, lẹ́yìn àìsàn rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn oníṣègùn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ìyẹn, Dr. Ameyo Adadevoh, ń rò ó pé ó ti ní àrùn Ebola, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sawyer ní òun ò ní àrùn náà. Oníṣègùn náà pinnu láti tì í mọ́ yàrá kan pẹ̀lú ìbójútó àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ìwòsàn náà.
Ní ọ̀sàn ọjọ́ kejì, èsì àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe jáde, wọ́n sì ri pe Sawyer tí kó àrùn Ebola. Ìròyìn yìí jáde síta, ó sì jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa kó àrùn náà ní Èkó, èyí sì mú kí àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn bẹ̀rẹ̀ sí ní kéde rẹ̀. Nàìjíríà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbáradì fún ìtànká àrùn náà.
Dr. Adadevoh pàdé Dr. Wasiu Gbadamosi, tó ń ṣàmójútó Yaba infectious facility, àti Dr. David Brett-Major láti World Health Organization. Ó ṣàkíyèsi pé Yasu facility ò ní àwọn irinṣẹ́ tó pé ye láti fi kojú àrùn náà. Ní July 25, àwọn oníṣègùn náà ṣàkíyèsi pé Sawyer ti kú. The First Consultants Medical Center sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wá ojútùú sí ìṣòro yìí, àti láti dáàbò bo àọn òṣị̀ṣẹ́ wọn.
Ìtàn náà dá lórí ìfarajìn tọkùnrin-tobìnrin tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀, láti ri dájú pé wọ́n borí àrùn náà, kí ó tó di àjàkálẹ̀ àrùn.[4]
|url-status=
ignored (help)