Bukola Oladipupo | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Adebukola Oladipupo 23 Osu Kaarun, 1994 London |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ | Covenant University |
Iṣẹ́ | Osere |
Adébùkọ́lá Ọládipúpọ̀ (tí a bí ní Oṣù Kaàrún Ọjọ́ 23, Ọdún 1994) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe rẹ̀ nínu eré MTV Shuga .
A bí Ọládipúpọ̀ ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù[1] ṣùgbọ́n ó ní ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Ìlú Èkó. Ó ní àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò méjì. Ọládipúpọ̀ lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Bellina Nursery and Primary School, Àkọkà, Ìlú Èkó. Ó tún lọ sí Ilé-ìwé Babcock High School àti Caleb International School fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ní Covenant University níbi tí ó ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ eré ìtàgé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìmọ̀ ìṣàkóso.[2]
Ó ṣe ìdánwò ní àṣeyọrí fún MTV Shuga ní ọdún 2015 níbití wọ́n ti fun ní ipa “Faa”.[3] Ó tọ́ka sí Mo Ábúdù tó kọ láti ní ìgbàgbọ́ nínu ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹni tí ó ṣe pàtàkì fún àṣeyọrí náà.[4] Ní ọdún 2015 ó ṣe àfihàn nínu apá kínní Indigo, Inevitable àti The Other Me.[5] Ní ọdún 2017 ó kópa nínu fíìmù Missing.[6]
Àwọn fíìmù tí ó ti ní lórúkọ rẹ̀ kún Moms at War, Phases (NdaniTV), The Men's Club, àti Africa Magic Forbidden.
Ọládipúpọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n sì n kópa lọ́wọ́ nínu MTV Shuga nígbà tí eré náà dín kù sí eré oníṣókí tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ni MTV Shuga Alone Together, èyí tí n ṣe àlàyé àwọn ìṣòro Coronavirus ní Oṣù Kẹẹ̀rin Ọdún 2020. Eré náà jẹ́ gbígbé sáfẹ́fẹ́ fún ọgọ́ta àṣálẹ́, àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ sì pẹ̀lú Àjọ Ìlera Àgbáyé.[7] Eré náà dá lóri Nàìjíríà, Gúúsù Áfríkà, Kẹ́nyà àti Cote D'Ivoire àti pé ṣíṣe rẹ̀ wáyé pẹ̀lú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àwọn olùkópa eré lóri ẹ̀rọ ayélujára. Gbogbo yíya àwòrán eré náà sì wáyé látọwọ́ àwọn òṣèré fúnrawọn.[8] Lára wọn ni Jemima Osunde, Lerato Walaza, Sthandiwe Kgoroge, Uzoamaka Aniunoh àti Mohau Cele.