Adegboyega Dosunmu II (CON) | |
---|---|
Reign | July 2005 – December 2021 |
Predecessor | Oba Adisa Odeleye |
Spouse | Mrs. Adetoun Dosunmu (nee Sanni) widowed
Mrs. Olatunbosun Dosunmu, (nee Oyetayo) |
House | Palace of the Olowu of Owu Kingdom |
Father | Benjamin Okelana Dosunmu |
Born | Owu kingdom, Ogun State South-Western Nigeria |
Died | December 2021 Abeokuta, Ogun state |
Adégbóyèga Dòsùnmú Amórorò II (CON) jẹ́ ọba ilẹ̀ Òwu ní ìpínlẹ̀ ògùn, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. À-pè-jálẹ̀ oyè rẹ̀ ni Olówùú ti ilẹ̀ Owú[1]. Ó gun orí oyè yìí nígbà tí Ọba Oláwálé Àdìsá Ọdẹ́lẹ́yẹ, Lágbedu wàjà ní oṣù kẹfà ọdún 2003 ní ẹni ọdún márùn-dín-láàádọ́rin[2].
Ọba Adégbóyèga Dòsùnmú jẹ́ ọmọ bíbí inú ọmọ ọba Benjamin Òkélànà Dòsùnmú (ọ̀kan lára àwọn ọmọ oyè ní ìran olóògbé Ọba Adésùńmbọ̀ Dòsùnmú, Amórorò Kínní) ẹni tí ó jọba láàárín ọdún 1918 àti 1924) ní ilẹ̀ Owú. Benjamin Òkélànà Dòsùnmú yìí ni ọmọ kẹta tí Ọba Adésùńmbọ̀ Dòsùnmú, Amórorò bí.
Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ìwé rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ìjọ Onítẹ̀bọmi ní Òwu (Owu Baptist Day School), Abẹ́òkúta ní ọdún 1941. Lẹ́yìn èyí, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti àwọn Baptist Boys’ High School, níbẹ̀ ni ó sì ti gba ìwé ẹ̀rí oníwèé mẹ́wàá ní ọdún 1950. Ó tẹ̀síwájú nínú ìwé kíkà rẹ̀ nígbà tí ó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ gba ìmọ̀ lórí eré orí-ìtàgé àti bí a tí ń ṣe ètò orí ẹ̀rọ-amóhùn-máwòrán Drama and Television Production ní ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ (Hendon College of Technology) ní ìlú Ọba (London) ní ọdún 1963. Lẹ́yìn èyí, ó tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ìlú Amẹ́ríkà láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn ìgbàlódé ní ilé-ẹ̀kọ́ Ìjọ Onítẹ̀bọmi tí ó wà ní ìlú Tennessee (Landmark Baptist College Tennessee, USA) níbẹ̀ ni ó ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì ní ọdún 1987.