Felicia Adetoun Ogunsheye | |
---|---|
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Felicia Adetowun Omolara Banjo 5 Oṣù Kejìlá 1926 Ilu Benin, Ipinle Edo |
Education | Queen's College, Eko Yaba College of Technology Yunifásítì ìlú Ibadan Yunifásítì ìlú Cambridge Simmons College |
O un tí a mọ̀ ọ́ fún | Òún ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ dé ipò ọ̀jọ̀gbọ́n |
Felicial Adetoun Omolara Ogunseye ( ti o je omobibi inu Banjo) ni a bi ni ojo karun un osu kejila odun 1926. Adetoun ni ojogbon obinrin akoko ni orile-ede Nàìjíríà. O je ojogbon onimo ijinle lori ile ikowe pamo si ka (Library and Information Science) ni ile-eko giga ti Yunifasiti ilu Ibadan.[1][2]
A bi Ogunseye ni ojo karun un osu kejila odun 1926 ni ilu Benin, orile-ede Nàìjíríà. Omo Ipinle Ogun ni awon obi re. O je egbon agba fun ogagun Victor Banjo ati Ademola Banjo. O lo si ile-iwe giga ti Queen ki o to di wipe o lo si koleji ti imo-ero ti o wa ni Yaba (Yaba College of Technology), nibi ti o ti je wipe oun nikan soso ni obinrin ni aarin awon akeko ni odun 1946. Adetoun ni obinrin akoko ti o koko keko gboye dipuloma jade ni ile-eko yi ni odun 1948. O lo si ile-eko giga Yunifasiti ilu ibadan ki o to di wipe o ni anfaani si eko ofe lo si ile-eko giga Newnham ti Yunifasiti ilu Cambridge ni orile-ede Geesi lati lo ko eko lori Geography. O gba oye akoko ti Yunifasiti (Bachellor of Art degree) ni odun 1952 ati oye eleekeji (Masters of Art degree) ni odun 1956 ni sise n tele ni ile-eko giga yi, nibi ti o ti je wipe oun ni obinrin akoko lati orile-ede Naijiria. O gba oye giga ti Yunifasiti eleekeji miran lori imo nipa ikowe pamo si ka lati ile-eko giga ti Simmons, ti o wa ni Massachusetts, USA ni odun 1962.
Adetoun ni o da ile ikawe ti Abadina Media Resources Centre ti o wa ni ile-eko giga Yunifasiti ilu Ibadan sile ni odun 1973. O di ojogbon ni ile-eko giga Yunifasiti ilu Ibadan. Ni Yunifasiti ilu Ibadan yi ni won ti yan an gege bi i oga agba ti eka eko laarin odun 1977 si odun 1979. Oun ni o je obinrin akoko ti won ma a koko yan gege bi oga agba ni ile-eko giga Yunifasiti kankan ni orile-ede Naijiria. O ti sise gege bi i onimoran fun orisirisi ile ise. Lara won ni Ile Ifowopamo ti agbaye (World Bank); International Federation of Library Associations and Institutions (IFLA); UNESCO; International Association of School Librarianship (IASL); International Federation of Documentation (FID) ati British Council.
Awon ola ati iyin orisirisi ni Adetoun Ogunseye ti gba. Lara won ati odun ti o gba won niwonyi:
Ile eko giga Yunifasiti Ibadan tun so gbongan ibugbe kan ti awon omo ile-eko n gbe ni oruko re ni akoko ti ojogbon Abel Idowu Olayinka n se isakoso ile-eko giga Yunifasiti yi.[3]