Aduke Alakija

Aduke Alakija
Lára àwọn aṣojú Nàìjíríà ní àjọ àgbáyé, United Nations
In office
1961–1965
Executive Secretary of the Lagos State Chamber of Commerce
In office
1967–1967
Aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè Sweden tẹ́lẹ̀ láti ọdún 1984 sí 1987
In office
1984–1987
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Jayéọlá Àdùkẹ́ Alákijà

March 1921
AláìsíMarch 2016 (aged 95)
Ọmọorílẹ̀-èdèNàìjíríà
Àwọn òbíAdéyẹmọ Alákijà (bàbá)

Jayéọlá Àdùkẹ́ Alákijà tí wọ́n bí lóṣù kẹta ọdún 1921,tí ó sìn kú lóṣù kẹta ọdún 2016 (March 1921 – March 2016) jẹ́ gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ Nàìjíríà tí ó fìgbà kan jẹ́ òṣìṣẹ́ alámọ́jútó, amọ̀fin àti aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè Sweden tẹ́lẹ̀ láti ọdún 1984 sí 1987. Bẹ́ẹ̀ náà ló fìgbà jẹ́ Ààrẹ àwọn ẹgbẹ́ Amọ̀fin-bìnrin, International Federation of Women Lawyers.

Ìgbésí-ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Àdùkẹ́ sí ìdílé Adeyemo Alakija, òun ni àbígbẹ̀yìn àti ọmọbìnrin kanṣoṣo tí bàbá rẹ̀ bí. Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Claxton House School, ní Marina, ní Èkó kí ó tó mórí lé orílẹ̀ èdè Wales lọ́dún 1930 fún ẹ̀kọ́ sí i níbi tí ó ti parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì rẹ̀ ní Penrhos College, lápá àríwá Wales. Ó kọ́kọ́ wùn ún kó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní Glasgow University ṣùgbọ́n ó wá pàpà lọ kàwé gboyè nínú ìmọ̀ àyíká ní London School of Economics. Ní kété tó padà sí Naijiria, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alámọ̀ọ́jútó ní ilé iṣẹ́ adájọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[1][2] Ní àsìkò rẹ̀, ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ẹjọ́ àwọn màjèsín àti ẹgbẹ́ àwọn ọmọbìnrin ní Ìpínlẹ̀ Èkó,[3] bẹ́ẹ̀ ló ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìdásílẹ̀ British Leprosy Relief Association èka Ìpínlẹ̀ Èkó. Lọ́dún 1949, ó tún padà sí òkè-òkun láti kàwé gboyè nínú ìmọ̀ òfin tí ó sìn di amọ̀fin lọ́dún 1953. Lẹ́yìn náà, ó dá ilé iṣẹ́ silẹ pẹ̀lú Gloria Rhodes, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣiṣẹ́ John Idowu Conrad Taylor. Nígbà tó yá, ó tún lọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alámọ́jútó àwùjọ, òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó di ipò yìí mú ní Nàìjíríà.[2]

Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ilé iṣẹ́ ìfọpo Mobil lọ́dún 1957.[3] Lọ́dún 1961, Mobil gba iṣẹ́ ìfọpo ni Nàìjíríà lọ́dún, wọ́n sìn fi í ṣe ọ̀gá yányán níbẹ̀. Lọ́dún 1967, ó di akọ̀wé àgbà olùdarí àjọ àwọn oníṣòwò káràkátà ti Ìpínlẹ̀ Èkó, Lagos State Chamber of Commerce. Lọ́dún 1961 sí 1965, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára aṣojú Nàìjíríà ní àjọ àgbáyé United Nations.

Àdùkẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ New Era Girls College, tí ó jẹ́ ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ International Women Society of Nigeria àti ọmọ ẹgbẹ́ Soroptimist International.

Wọ́n fún ní oyè dìgírì ní Barnard College.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Alakija, Aduke". 2005. In The Palgrave Macmillan Dictionary of Women's Biography, edited by Jennifer S. Uglow, Frances Hinton, and Maggy Hendry. Basingstoke: Macmillan Publishers Ltd.
  2. 2.0 2.1 Balogun, Hairat (April 12, 2016). "Ambassador Jaiyeola Aduke Alakija, A Toast and Tribute". Thisday (Lagos). 
  3. 3.0 3.1 Little, Kenneth. African Women in Towns: An Aspect of Africa's Social Revolution. p. 203.