Adéníkẹ̀ẹ́ Grange | |
---|---|
Ilé-iṣẹ́ ètò ìlera ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Federal Minister of Health) | |
In office 26 July 2007 – 26 March 2008 | |
Asíwájú | Eyitayo Lambo |
Arọ́pò | Babatúndé Oṣótìmẹ́yìn |
Adenike Grange jẹ́ Mínísítà àná fún ètó ìlera lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọdún 2007 sí 2008.
Adéníkẹ̀ẹ́ Grange kàwé ní ìlú Èkó kí ó tó kọjá sí St. Francis' College, Letchworth ní United Kingdom láti tẹ̀ síwájú. Ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó lọ́dún 1958 sí 1964 ní University of St Andrews lórílẹ̀-èdè Scotland. Ó ṣiṣẹ́ ní ilé-ìwòsàn Dudley Road Hospital ní Birmingham kí ó tó padà sí Nàìjíríà lọ́dún 1965, tí ó sìn ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé-ìwòsàn ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó tún padà sí òkè-òkun, United Kingdom lọ́dún 1967, tí ó sìn ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dókítà àwọn ọmọdé St Mary's Hospital for children. Ó kàwé gboyè dípólómà si nínú ìmọ̀ ìlera ọmọdé lọ́dún 1969. Lọ́dún 1971, ó dára pọ̀ mọ́ Lagos University Teaching Hospital, ó sìn di olùkọ́ ní Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ (College of Medicine) , Lọ́dún 1978 ní University of Lagos. Ó di olùkọ́ àgbà lọ́dún 1981,bẹ́ẹ̀ náà ó di Ọ̀jọ̀gbọ́n lọ́dún 1995.[1]
Adéníkẹ̀ẹ́ Grange ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbani-nímọ̀ràn sí ilé-iṣẹ́ ètò ìlera ìjọba àpapọ̀, Federal Ministry of Health, WHO, UNICEF, UNFPA àti USAID.[2] Òun ni olùdámọ̀ràn sí àjọ WHO ní Nàìjíríà lórí ètò ìlera ọmọ bíbí láti ọdún 1993 sí 1999. Ó ti kọ ju ìwé àádọ́ta lọ lórí ètò ìlera, pàápàá jù lọ lórí àìsàn diarrhoeal àti ètò oúnjẹ ẹ̀tọ́ fún ọmọdé. Ó jẹ́ Ààrẹ fún ẹgbẹ́ International Paediatric Association.[3] Lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí aṣègbè fún ìlera tó péye fún àwọn ọmọdé.[4]
|url-status=
ignored (help)