King Abipa/Ogbolu or Oba M'oro | |
---|---|
Orúkọ míràn | Oba M'oro |
Iṣẹ́ | Alaafin of the Oyo empire |
Aláàfin Abípa, òun ni a tún mọ̀ sí l Ògbólú tàbí Ọba Moró,[1] jẹ́ Àlááfín Ọ̀yọ́ àti àgbègbè rẹ̀. Wọ́n gbà pé ó wà ní ìtẹ́ ọba Àlááfín ní nǹkan bí sẹ́ńtúrì 16 àti 17. [2]
Àlááfín Abípa jẹ́ ọmọ bíbí was the son of Egunoju àti ọkàn nínú àwọn olorì rẹ̀. Wọ́n ní wón bí i lọ́nà lọ́jọ́ tí wọ́n ń ṣayẹyẹ kan lọ́nà àtisúnmọ́ ìlú Igboho (wọ́n fún lórúkọ láti inú ọ̀rọ̀ yìí a bí i sí ipà - 'ẹni tí wọ́n bí sí ipà ọ̀nà tàbí ẹ̀bá ọ̀nà').[2]
Kí ó tó di àkókò rẹ̀ ọba mẹ́ta tí jẹ́ lórí Ọ̀yọ́ sí Ìgbòho dípò Ọ̀yọ́ ilé nítorí ìbẹ̀rù àwọn Nupe àti àwọn mìíràn. Abípà ni Àlàáfíà Ọ̀yọ́ tí ó dá olú-ìlú Ọ̀yọ́ padà sí Ọ̀yọ́-ilé lẹ́yìn tí wọ́n ti borí àwọn ogún ti ó ń jàwọ́n láti ìta. Pípadà sí Ọ̀yọ́-ilé wáyé ní sẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún (17 Century).[3]
Gẹ́gẹ́ bí àṣà, àwọn ènìyàn pàtàkì kan tí wọ́n fẹ́ kí olú-ìlú Ọ̀yọ́ ṣì dúró sí Ọ̀yọ́-Ìgbòho rán àwọn olórò òfegè láti lọ ṣe aṣojú ọfegè nígbà tí àwọn ènìyàn Abípà ṣe àbẹ̀wò sí olú-ìlú àtijọ́.[4] Abípà mọ nípa èyí, ló bá rán àwọn ọdẹ lọ láti mú àwọn olórò òfegè wọ̀nyí. Nítorí èyí ni wón ṣe ń pè é ní Ọba mórò, Ọba tí ó mú orò. Ìtàn yìí ṣì ń jẹyọ lásìkò ọdún ni Ọ̀yọ́ àti nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi ọba Àlááfín tuntun jẹ.[4]
Nígbà tí ọdún òye wọ Ọ̀yọ́-ilé, Abípà fi ọmọkùnrin aṣẹ̀ṣẹ̀bí rúbọ. Ìdí nìyí tí wón fi máa ń kì í ní "Ọba amórò tó f'ọmọ rẹ̀ rúbọ fún àlàáfíà ayé'.[4]
Obalokun ló j'ọba lẹ́yìn rẹ̀.Àdàkọ:Cn