Alaba Lawson | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kínní 1951 Abeokuta, Ogun State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Iyalode Alaba Lawson |
Iléẹ̀kọ́ gíga |
|
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 1977–present |
Employer | NACCIMA |
Board member of | Chairman, Board of Governing Council, Moshood Abiola Polytechnic, Ogun State |
Website | alabalawson.org |
Olóyè Alaba Lawson (tí a bí ní Omidan Alaba Oluwaseun Lawson ni ọjọ kejì-dín-lógún oṣú kínní ọdún 1951) jẹ ọmọ orilẹ-èdè Naijiria; olokoowo nla, oniṣowo agba ati ọmọwe sì ni pẹlu. Òun ni ó jẹ́ obinrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ aarẹ ẹgbẹ NACCIMA ati Alága Ìgbìmọ̀ awọn Alakoso ti ile ẹko gbogboniṣe, Moshood Abiola ni Ìpínlẹ̀ Ogun ni orilẹ-ede Naijiria.
Olóyè Lawson ti di ipo aarẹ agbarijọpọ awọn lọbalọba to jẹ́ obinrin ni orilẹ-ede Naijiria (Forum of Female Traditional Rulers in Nigeria).
A bi Alaba si inu ẹbi Jibolu-Taiwo ti ìlú Abeokuta, ti i ṣe olu ilu fun ipinlẹ Ogun, níbi ti o ti pari ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ni ile-ẹkọ St. James’ African Primary School, Idi-Ape, Abeokuta laarin ọdun 1957 ati 1962 fun ẹkọ alakọbẹrẹ ati Ile-ẹkọ girama fun awọn obinrin (Abeokuta Girls Grammar School), Abeokuta, eleyi ti o pari ni ọdun 1968[1] ki o to tẹsiwaju lati lọ si ile ẹkọ fun awọn olukọni ni St. Nicholas Montessori Teachers’ Training College ti o wa ni Prince's Gate, England ni ọdun 1973 ni bi ti o ti peregede ti o si gba iwe ẹri diploma ninu ikọni (Diploma in Education)[2].