Ọdarawu fìgbà kan jẹ́ Aláàfin Ìlú Ọ̀yọ́, ní sẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún.[1] Òun ni Aláàfin àkọ́kọ́ tí àwọn Ọ̀yọ́ Mèsì ò tẹ́wọ́gbà.[1]
Ọdarawu jẹ́ ọmọ Aláàfin Àjàgbó. Kò pẹ́ rárá lórí oyè. Ó jẹ́ onínú fùfù, tó máa ń tètè bínú. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, ìbínú rẹ̀ ló sun dé bí wọ́n ṣe le kúrò lórí oyè, tí ó sì dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ fún àwọn ọba tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀. Ogun tí Ọdarawu kópa nínú rẹ̀ ni èyí tó ṣe kẹ́yìn. Lásìkò ìjọba rẹ̀, ó pàṣẹ kí wọ́n ba ọjà kan jẹ́. Orúkọ ọjà yìí ni Ojo-segi, nítorí ọkàn lára àwọn tó ń tajà níbẹ̀ ṣèṣì gbá Aláàfin yìí létí láìmọ̀ pé òun ni Aláàfin, tí ó sì tún pè é ní olè.[2] Lẹ́yìn gbogbo awuyewuye yìí, àwọn ará Ọ̀yọ́ ní kó ṣígbá wò, nítorí kò yẹ láti ṣèjọba ìlú Ọ̀yọ́.
Lẹ́yìn tó wàjà, Aláàfin Kánran jẹ oyè Aláàfin.