Anellovirus | |
---|---|
Ìṣètò ẹ̀ràn | |
Group: | Group II (ssDNA)
|
Ìdílé: | Anelloviridae
|
Genera | |
Alphatorquevirus |
Anelloviridae jẹ́ ẹbí àwọn àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Wọ́n kàwọ́n sí àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn tí ó légungun tí ó sì ní ẹ̀wù ìdáàbòbò tí o gbó dáradára, tí ó rí róbótó, tí igun rẹ̀ jọ ara wọn, pẹ̀lú ogún igun tó jọrawọn. Àwọn ẹ̀yà wọ̀n yí jẹ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn ti torque teno (ìdílé Alphatorquevirus).[1]
Iye jíìnì ẹ̀ ko pín sí wẹ́wẹ́ tí ó sì ní molecule róbóto, pẹ̀lú apá DNA kan. Gbogbo iye jíìnì rè. jẹ́ bíi 3000 sí 4000 gígun ne nucleotide.[2]
Anellovirus jẹ́ àwọn ẹ̀yà tí ó wọ́pọ̀ tí ó sì pé oríṣiríṣi. Wọ́n maa ń fa àkóràn nlá tí a kò tíì mọ ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àìsàn.[3] Ẹbí mẹta ni ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àkóràn ènìya: kòkòrò àìlèfojúrí ti Torque teno (TTV), kòkòrò àìlèfojúrí pélébé ti Torque teno midi (TTMDV) àti kòkòrò àìlèfojúrí mini ti (TTMV).