Anita Kyarimpa jẹ́ òṣèré, atọkun ètò àti oníṣòwò lórílẹ̀ èdè Uganda.[1] Ní oṣù kejì ọdún 2019, ilé iṣẹ́ Goodwill Tourism fi ṣe àmbásẹ́dọ̀ wọn[2]. Kí ó tó ṣe atọ́kun fún ètò Bẹ my Date lórí NTV ní ọdún 2014, ó ti jẹ ipò omidan Uganda tí apá iwọ̀ òrùn. Ó gbé ipò kejì níbi ìdíje omidan Uganda[3]. Ó ti ṣe atọ́kun fún àwọn ayẹyẹ bíi Africa Magic Viewer’s Choice Awards ní Nigeria (2016), Namibia Annual Music Awards (2016 àti 2017), Ghana Movie Awards 2017, Ghana Music Awards 2016,[4] àti Glitz Awards Ghana 2017.[5]
Anita bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mọ́dẹ́lì nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún méjìlá, ó sì ṣíṣe pẹ̀lú Flair Magazin ní ọdún 2008.[6] Ní ọdún 2013, ó kópa nínú ìdíje omidan Uganda, ó sì gbé ipò kejì[7]. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe agbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí tẹlẹfíṣọ̀nù ní ọdún 2014 pẹ̀lú ètò Be My Date[8]. Fabiola gbajúmọ̀ fún ipa Angelina tí ó kó nínú eré Second Chance ní ọdún 2016[9]. Òun ni atọ́kun ètò Katch Up lórí NBS TV.[10] Ní ọdún 2018, ó di ọmọ orílẹ̀ èdè Uganda àkọ́kọ́ tí wọ́n má pè síbi ayẹyẹ Cannes Film Festival.[11] Ó gbé ètò The Fabiola Podcast kalẹ̀.[12] Ní oṣù kejì ọdún 2019, wọ́n fi ṣe àmbásẹ́dọ̀ fún Tulambule[13][14][15]. Ó tún jẹ́ àmbásẹ́dọ̀ fún CAT footwear,[16] Paramour Cosmetics, Lux Belaire, Virginia Black MTN Pulse, Jumia Uganda àti Lauma Uganda.[17] Fabiola dá ẹgbẹ́ Fab Girls Foundation kalẹ̀ láti lè má pèsè iranlọwọ fún àwọn obìnrin.[18][19]