Annie Macaulay–Idibia | |
---|---|
2014 | |
Ọjọ́ìbí | 13 Oṣù Kọkànlá 1984 Ibadan, Oyo State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ẹ̀kọ́ | Yunifásítì ìlú Eko Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èko |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 2009–present |
Olólùfẹ́ | Innocent Idibia |
Annie Macaulay-Idibia (tí a bí ní 13 Oṣù kọkànlá ọdún 1984) jẹ́ afẹwàṣiṣẹ́ àti òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Wọ́n yàán fún àmì-ẹ̀yẹ ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jù níbi ayẹyẹ Best of Nollywood Awards ti ọdún 2009.[3]
A bí Annie ní Ìbàdàn ṣùgbọ́n ó wá láti Ìlú Eket ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom. Ó kó lọ sí Ìlú Èkó pẹ̀lú ìyá rẹ̀ lẹ́hìn ìpínyà láàrin àwọn òbí rẹ̀. Ó ní oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmò kọ̀mpútá sayẹnsì àti eré tíátà, èyí tí ó gbà láti ilé-ìwé gíga Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èko àti Yunifásítì ìlú Èkó.[4]
Ṣáaj́u kí Annie Macaulay-Idibia tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀, ó ti díje níbi Queen of All Nations Beauty Pageant níbití ó ti ṣe ipò kejì, ó sì tún ti hàn nínu orin kan ti 2face Idibia tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ African Queen.[4]
Ó di gbajúmọ nídi iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní Nollywood lẹ́yìn kíkópa nínu àwọn sinimá táa pè àkọ́lé wọn ní Pleasure and Crime àti Blackberry Babes.[4]
Annie Macaulay – Idibia ti ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú 2face Idibia tó sì ti bí ọmọ méjì fun. Ó bí ọmọ àkọ́kọ́ rẹ̀, ọmọbìnrin tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Isabella Idibia, ní Oṣù kejìlá Ọdún 2008 àti ọmọ èkejì tí orúkọ ti òun n ṣe Olivia Idibia ní Oṣù Kíní, Ọdún 2014.[6][7] Ó ní ilé ìṣọ̀ṣọ́ kan ní ìlú Atlanta tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ "BeOlive Hair Studio".[8]
Ọdún | Ayẹyẹ | Ẹ̀ka | Èsì |
---|---|---|---|
2009 | 2009 Best of Nollywood Awards | Best Supporting Actress | Wọn pee |
2016 | African Entertainment Legend Awards | Fast Rising Actress | Gbaa |