Ataare jẹ́ ata, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èròjà fún ṣíṣe ọbè ní ilẹ̀-Adúláwọ̀.[1]Ó sì wúlò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan bíi iṣẹ́ àmúṣagbára àti fífi ṣe ìwúre láwùjọ Yorùbá.
Wọ́n ń lo ó láti fi se ọbẹ̀. Tí wọ́n bá fẹ́ fi se ọbẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ gun nínú odó kí wọ́n tó dà á sínú ọbẹ̀.[2]
Nínú àṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ Yorùbá, àwọn Yoruba máa ń lò ó láti fi ṣàdúrà fọmọ titun.Tí àdùrá na lọ báyìí "Ataare kì í di tirẹ̀ láàbọ̀ kíkún ni ataare n kún, ayé rẹ a kún fówó, ayé rẹ a kún fọ́mọ, ayé rẹ a kún fún onírúurú dúkìá jìngbìnnì.
Ní ilẹ̀ Igbo, àwọn Igbo náà máa ń lò ó fún ìsọmọlórúkọ.
Nínú ìgbàlejò, wọ́n a máa ń fún àwọn àlejò ní Obì, àti ataare, wọ́n á sì fi ṣàdúrà.[3]