A.Y | |
---|---|
![]() | |
Ọjọ́ìbí | Ayo Makun 19 Oṣù Kẹjọ 1971 Ondo State, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Comedian |
Gbajúmọ̀ fún | Being Mrs Elliot[1][2][3] |
Olólùfẹ́ | Mabel Makun |
Àwọn ọmọ | Michelle Makun |
Ayodeji Richard Makun, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ AY, jẹ́ òṣèré ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, apanilẹ́rìn-ín, òńkọ̀wé, olóòtú àti olùdarí ere,́ ó sì máa ń ṣe ètò lórí rédíò àti lórí ẹ̀rọ̀ amóhùn-máwòrán. Ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1971 ni a bí Ayo.[4] Ìlú Ifon, ti ìjọba ìbílẹ̀ Ose ní Ìpínlẹ̀ Òndó ni ó ti wá. Òun ni agbátẹrù ètò “AY live shows” àti ”Ay comedy skits”. Fíìmù àgbéléwò àkọ́kọ́ rẹ̀ ni 30 Days in Atlanta,[5] òun sì ni olóòtú fíìmù náà, àmó, Robert Peters ni olùdarí rẹ̀. Ó ti fìgbà kan rí jẹ́ aṣojú àlááfíà àwọn UN[6]