Baptist Boys’ High School | |
Ère akẹ́kọ́ Baptist Boys’ High School | |
Location | |
---|---|
Oke-saje Abeokuta, Ogun, Nàìjíríà | |
Information | |
Type | Gbogboògbò |
Established | 1923 |
Enrollment | 75 (1923) |
Baptist Boys’ High School jẹ́ ilé ìwé girama ní Abeokuta, Ìpínlẹ̀ Ògùn, gúúsù-ìwọ oòrùn Nàìjíríà. Ó ní àwọn akẹ́kọ ẹgbẹ̀rún lé ọgọ́rún ní ọdún 2011 sí 2012.[1] Àwọn akẹ́kọ yìí dínkù dé ìdajì láti 2155 ní ọdún 1998 sí 1999,[2] látàrí láti ri wípé kí oun èlò fún ẹ̀kọ́ lè tó won. BBHS wà ní ibùdó rẹ̀ ní Oke-Saje.
Baptist Boys’ High School di dídásílẹ̀ nípasẹ̀ àpérò[3] àwọn ará Amẹ́ríkà ti Gúúsù Baptist tí wọ́n bẹ̀ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìlú Abeokuta ní ọjọ́ karún Oṣù kẹjọ, Ọdún 1850 àti díde àlùfáà Thomas Jefferson Bowen[4][5] tí ó jẹ́ ajíyìnrere àkọ́kọ́, àti oníwàásùn ìyìnrere, ará Amẹ́ríkà ti Gúúsù Baptist sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ṣètò ilé ìwé, ileŕ ìwòsàn, ilé ìwé fún àwọn olùkọ́ àti ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn tí ó fẹ̀ ní ìmọ̀ nípa bíbélì.[4][6][6][7][7] Ìrìnàjò Baptist ti ilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ ẹ̀ka tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tí ó dá ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ mẹ́ta sílẹ̀ sí Ago-Owu, Ago-Ijaye àti Oke-saje [8]
Lẹ̀yín tí àwọn akẹ́kọ́ tí ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ tí Owu gbòòrò sí 150,[9] wọ́n sọ́ fún Àlùfáà Samuel George Pinnock kí ó dá ilé ìwé tí ó ga ju alákọ́bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀.[8] Ní ọdún 1916 Pinnock ṣe àwárí ibùdó, Oke Egunya , tí ó sì ra ilẹ̀ náà. Kíkọ́ ilé ìwé yìí kò yára rárá nítorí ogun àgbáyé tí ó jẹ́ kí gbogbo nkan ìkọ́lé gbówó lórí.[9] Bákan nán, ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ọdún 1922 Pinnock ríi dájú wípé ibùgbé olórí ilé ẹ̀kọ́ náà di kíkọ, tí ó sì tún jẹ́ ilé àwọn ajíyìnrere tí Abeokuta; yàrá ìkàwé márún, ilé ìjọsìn àti yàrá fún àwọn ọkùnrin.
Ní ọdún 1922 Pinnock ṣa àwọn akẹ́kọ́ tí ó ti ní ìmọ̀ díẹ̀ láti Ago-Owu, Ago-Ijaye àti Oke-saje, tí wọ́n sì jẹ́ àkẹ́kọ́ àkọ́kọ́ ní gírama yìí.[8] Ó sí Baptist Boys’ High School ní ọjọ́ kẹtàlélógún Oṣù kínín Ọdún 1923, pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ 75 àti olùkọ́ mẹ́rin (pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, Madora Pinnock).[8] Àwọn ẹgbẹ̀rún méjì ènìyàn ló wá sí ibi ayẹyẹ náà. Àléjò pàtàkì tí ó sọ̀rọ̀ níbẹ̀ ní Ọ̀jọ̀gbọ́n Professor Nathaniel Oyerinde,[8] tí ó jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Baptista,[9] Ogbomoso, tí ó sì jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Baptist àkọ́kọ́ ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[10]
Wọ́n dá Baptist Boys’ High School sílẹ̀, tí ó sì wà bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ilẹ́ ìwé fún àwọn ọkùnrin, bíótilẹ̀jẹ́ wípé wọ́n kó àwọn obìrin mọ́ wọ́n ní ọdún 1969 àti 1970, nígbà tí àwọn àjọ gómìnà dá Higher School Certificate sílẹ̀.[11] Ilé ìwé yìí gbòòrò sí 400 ní oṣù kejìlá ọdún 1946,[12] àti sí 1110 [1] ní bí ọdún 2011 sí 2012.
BBHS Old Boys Association ní ẹ̀ka sí UK/Ireland, USA/Canada, Abeokuta, Ibadan, Ijebu Ode, and Abuja.