Ìkọ kedere
Benedict Peters | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Benedict Peters 5 Oṣù Kejìlá 1966 Abakaliki,Ebonyi State, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ẹ̀kọ́ | Geography and town planning |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Benin, Benin |
Iṣẹ́ | Founder and Executive Vice Chairman, Aiteo Group |
Ọmọ ìlú | Agbor, Delta State, Nigeria |
Net worth | $2.7 billion (February 2016) [1] |
Àwọn ọmọ | 4 |
Website | http://www.benedict-peters.com |
Benedict Peters jẹ́ olówó billionaire, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2] Oun ni ó dá ilé iṣẹ́ Aiteo Group sílẹ̀. Ilé iṣẹ́ tí ó níṣe pẹ̀lú iṣẹ́ epo rọ̀bì tí ó jẹ́ ti àdáni tí ó sì tóbi jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3] Ní nkan bí oṣù Kọkànlá ọdún 2014, Benedict ti ní to iye owó tí ó to bílíọ́nù méjì ó lé ọwọ́ méje Dólà ($2.7 billion), gẹ́gẹ́ bí owó ara ẹni[4] Oun ni ó wà nípò Kéje gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó lówó jùlọ nileẹ̀ Adúláwọ̀, gẹ́gẹ́ bí àjọ Ventures Africa ṣe tòó sí. "The Richest People in Africa" Archived 2021-05-17 at the Wayback Machine..
Peters jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Delta, tí wọ́n sì bi ní ìlú Abakaliki, ní Ìpínlẹ̀ Ebonyi, sí inu ẹbí oníṣẹ́ ilé ìfowópamọ́.[5] Ó lọ sílé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ekulu ní ìlúEnugu, ṣáájú kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ oníwé mẹ́wàá ti Federal Government College Enugu, tí ó sì tẹ̀ síwájú ní after which he proceeded to Fásitì Benin, níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí Dìgírì (B.Sc) nínú ìmọ̀ Jọ́gíráfì àti Ìfètò sí àwùjọ (Geography and Town Planning).[6]
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní inẹ̀rẹ̀ ọdún 1990, nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Ocean Oil tí ó yí padà sí Oando Nigeria Plc nísìín, Iyán àwọn bí Adéwálé Tinubú, Mofẹ́ Báyọ̀ àti Onajite Okoloko. [7] Ó tun bá ilé-iṣẹ́ MRS Oil Nigeria PLC ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adarí àgbà, ṣáájú kí ó tó kúrò lọ dá ilé-iṣẹ́ Sigmund Communecci sílẹ̀ ní ọdún 1999. [8]. Ó dá ilé-iṣẹ́ Aiteo sílẹ̀ ní ọdún 2008, èyí tí ó jẹ́ ẹ̀ka Sigmund Communecci. [9][10][11] [12]