Bovi Ugboma | |
---|---|
![]() Bovi at the Africa Magic Viewers Choice Awards in July 2014. | |
Orúkọ àbísọ | Abovi Ugboma |
Ìbí | Benin City, Edo, Nigeria | Oṣù Kẹ̀sán 25, 1979
Genres | Acting, comedy |
Spouse | Kris Asimonye Ugboma |
Ibiìtakùn | bovitv.com |
Bovi jẹ́ aláwàdà, òṣèré, àti ònkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,[1] Ó ti gbé ètò Man on Fire kan tó gbajúmọ̀ jákè-jádò agbáyé.[2]
Bovi Ugbona ni wọ́n bí nu ìlú Bìní tí ó jẹ́ olú Ìlú fún Ìpínlẹ̀ Ẹdó, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti UNIBEN ní ọdún 1991, ó tún wọlé sílé-ẹ̀kọ́ ti Ìjọba àpapọ̀ Ìlú Ugheli ní Ìpínlẹ̀ Delta, àwọn òbí rẹ̀ mu kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ yí lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Edokpolor ní ìlú Bìní tí wọn ń gbé, kí wọ́n lè baà mójú to. Àmọ́ ẹ̀kọ kó ṣojú mímu fun ni wọ́n bá tún mu sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Onicha-_Olona. Lẹ́yìn tí ó parí ilé-ẹ̀kọ́ náà, ó wọ ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì ní ọdún 1998 ní Ìpínlẹ̀ Delta níbi tí ó ti kẹ́kòọ́ nípa eré-oníṣẹ.[3]
Ó bérẹ̀ iṣẹ́ àwàdà ṣíse ní inú oṣù Kẹrin ọdún 2007,[4] níbi tí ó ti kọ́kọ́ fara hàn nínú eré Extended Family,[5] tí ó jẹ́ wípé òun náà ni ó kọọ́ tí ó darí rẹ̀ tí ó sì gbe jáde. [6] eré náà gbajúmọ̀ gidi, nígbà tí yóò fi di ọdún 2008, Bovi ti ń kópa nínú àwọn ètò ọlọ́kan-ò-jọkan káàkiri ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[7] Ó di gbajú-gbajà látàrí ipa rẹ̀.nínú ètò Nite of 1000 Laughs tí ọ̀gbẹ́ni Opa Williams gbé kalẹ̀ ní ọdún 2013. Nínú ètò kan tí òun náà gbé kalẹ̀ tí ó pè ní Bovi- Man on Fire ní ọdún 2014, ni ó ti ṣe àfihàn àwọn òṣèré olórin jànkàn-jànkàn bí Jarule àti Ashanti hàn. Ètò yí ti fún Bovi ní ànfaní láti ṣe ìrìn-àjò lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè bíi Amẹ́ríkà, London, Melbourn àti Toronto ní ọdún 2017. Lẹ́yìn tí ó padà dé sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2019, ó bẹ̀rẹ̀ ètò míràn tí ó pè ní "BACK TO SCHOOL Bovi ti ní ìbáṣepọ̀ tó Yanrantí pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ní inú iṣẹ́ àwàdà bí : I Go Dye, I Go Save, Basketmouth, Buchi, Odogwu, Okey Bakassi, Julius Agwu àti bẹ̀ẹ́ bẹ̀ẹ́ lọ.[8]
Bovi kọ́kọ́ gbé eré rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde tí ó pè ní It's Her Day ní ọjọ́ Kẹsàán oṣù kẹsàán ọdún 2016.[9]Wọ́n yàn án fún amì-ẹ̀yẹ AMVCA gẹ́gẹ́ bí aláwàdà tó peregedé jùlọ. Wọ́n tún yàn án fún amì-ẹ̀yẹ yí fún ìgbà kẹta fún iṣẹ́ tí ó yàn láàyò.[10]
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)