Bukky Wright tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ Olúwabùkọ́lá Sekinat Àjọkẹ́ Wright (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 1967) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin, olùṣòwò ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2]
Bukky Wright | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oluwabukola Sekinat Ajoke Wright 31 Oṣù Kẹta 1967 Abeokuta, Ogun State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian (1967 - present) |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1996-present |
Bukky bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 1996. Láti ìgbà náà ló ti kópa nínú àìmọye sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì. Ó tún kópa nínú eré orí ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n tí gbajúgbajà onísinimá, Wálé Adénùgà máa ń ṣàfihàn, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Super Story". Ó ti gba oríṣiríṣi àmìn ẹ̀yẹ lórí ìṣe sinimá àgbéléwò. Yàtọ̀ sí ìṣe tíátà, Bukky Wright tún ní ilé iṣẹ́ aránṣọ ìgbàlódé àti oge ṣíṣe. [3] [4]
|url-status=
ignored (help)