Catherine Obianuju Acholonu | |
---|---|
Fáìlì:Catherine Obianuju Acholonu.jpg | |
Ọjọ́ìbí | 26 Oṣù Kẹ̀wá 1951 |
Aláìsí | 18 March 2014 | (ọmọ ọdún 62)
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Düsseldorf |
Catherine Obianuju Acholonu (tí a bí ní ọjọ́ kẹrindínlógún oṣù Kẹ̀wá ọdun 1951 – ọjọ́ méjìdínlógún oṣù kẹta ọdun 2014) jẹ́ Olùkọ̀wé, olóṣèlú àti ajàfẹ́to ẹni ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Òun ni Senior Special Adviser (SSA) sí ààrẹ Olusegun Obasanjo lórí ọ̀rọ̀ àwòrán àti àsà, ó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Association of Nigerian Authors (ANA).[2][3]
A bí Catherine sínú ìdílé Chief Lazarus Emejuru Olumba àti Josephine Olumba, ní Umuokwara Village, ti ìlú Orlu.[4][5] Òun ni àkọ́bí nínú àwọn ọmọ mẹ́rin.[6]
Ó parí ẹ̀kọ́ Primari àti Sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀ ní ilé-ìwé Holy Rosary School, kí wón tó fe fún Brendan Douglas Acholonu nígbà tí ,ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún, Douglas jẹ́ onísẹ́ abẹ, Orílẹ̀-èdè Jẹ́mánì sì ló kalẹ̀ sí nígbà náà.[4][5]
Ní ọdun 1974, Catherine tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Yunifásítì ti Düsseldorf, ó sì kékọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ìwé náà lodun 1977.[4] Ní ọdun 1982, ó gba àmì-èye PhD nínú ìmò èdè Igbo.
Acholonu fi ayé sílè ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta 2014, ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógota nígbà náà, ó kú látàrí àìsàn Kíndìnrín.[7]