Chico Ejiro (tí a bí ní Chico Maziakpono; kú lójó 25 Oṣù Kejìlá ọdún 2020) jẹ́ oludarí fíìmù Nàìjíríà , ònkọ̀wé eré ìtàgé, àti olupìlẹṣẹ̀. Ejiro jẹ́ ọmọ Isoko, Delta, Nàìjíría, tí ó kọ èkọ́ iṣẹ-ogbin ní ilé ìwé Èkó gíga. Ara iṣẹ́ nlá rẹ̀ jẹ́ aṣojú ti iran keji ti o bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1990 nígbàtí ohun èlò ìṣelọ́pọ̀ fídíò olówó pókú ti bèrè sí ní wà ní orílẹ̀-èdè náà. [1]
Wón má ń pe ní Mr. Prolific. Ó ṣe ìtọ́sọ́nà àwọn fíìmù tí o ju 80 lọ láàrin àkókò ọdún márún. Ó ṣe àfihàn àwọn ìtàn tí ó ní ìbátan pẹ̀lú àwọn ọmọ Nàìjíríà. Wọ́n gbe sí inú ìwé ìròyìn The New York Times, ati Iwe ìròhìn Time Magazine ni ọdún 2002.[2] [3]
Ìyàwó rè ni Joy Ejiro, tí wọ́n sì bi ọmọ mẹ́rin. Ó ní àwọn ọmọ ìyá méjì: Zeb Ejiro, ati Peter Red Ejiro.[4]
Ejiro ṣẹ ìfihàn nínu ìwé ìpamọ́ 2007 Welcome to Nollywood, eyiti o sọ bí o ṣe ṣe Family Affair 1 àti Family Affair 2.