Chioma Omeruah | |
---|---|
Fáìlì:Chioma Omeruah in 2022.png Chigul in 2019 | |
Ọjọ́ìbí | Chioma Omeruah 14 Oṣù Kàrún 1976 Ikeja |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Chigul |
Ẹ̀kọ́ | Delaware State University |
Iṣẹ́ | Teacher, Singer, Comedian, Actress |
Gbajúmọ̀ fún | Voices and characters |
Chioma Omeruah, tí a mọ̀ orúkọ ìnagi rẹ̀ sí Chigul, jẹ́ apanilẹ́rìn-ín, akọrin, àti òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ fún àwọn ipa apanilẹ́rìn-ín rẹ̀ tí ó maá n sábà ṣe ní gbogbo ìgbá
Wọ́n bí Omeruah sí ìlú Èkó. Òun ni àbílé kejì nínu àwọn ọmọ mẹ́rin ti àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ ni Samson Omeruah.[1]
Ó lọ sí ilé-ìwé girama méjì kan ní ìlú Jọs àti ní ìlú ìkẹjà,[2] ó sì tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Ábíá fún oṣù mẹ́ta, sááju kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ̀ gíga Delaware State University níbití ó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ nípa òfin tó de àwọn ìwà òdaràn.[3][4] Nítorí àìṣedédé rẹ̀ nínu ẹ̀kọ́ náà, ó padà tún kẹ́kọ̀ọ́ èdè Faransé láti ilé-ìwé Delaware State University bákan náà. Ó padà sí Nàìjíríà lẹ́hìn tí ó ti lo ọdún méjìlá ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà[5]
Ó kọ́kọ́ di akọrin lábẹ orúkọ C-Flow ṣùgbọ́n orúkọ Chigul bo ti tẹ́lẹ̀ mọ́lẹ̀ lẹ́hìn kíkó àwọn ipa apanilẹ́rìn-ín rẹ̀ nínu àwọn eré. Àkọ́lé àkọ́kọ́ orin rẹ̀ tí ó kọ ni "Kilode", èyí tí ó ṣe pẹ̀lú gbígbohùn rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì pín fún àwọn òrẹ́ rẹ̀.[6] Ó tí kópa nínu eré Nollywood kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Road to Yesterday.[7]
Odun | Aamì-ẹ̀yẹ | Ìsọrí | Esi | Ref |
---|---|---|---|---|
2021 | Net Honours | Most Popular Media Personality (female) | Wọ́n pèé | [9] |