Chike | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Chike-Ezekpeazu Osebuka |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Chike |
Ọjọ́ìbí | 28 Oṣù Kínní 1993 Lagos, Lagos State, Nigeria |
Irú orin | Highlife, RnB |
Occupation(s) | Singer, Songwriter, Actor |
Instruments | Vocals |
Years active | 2009–present |
Associated acts | Phyno, Ric Hassani, Simi, Mayorkun, Gyakie |
Chike-Ezekpeazu Osebuka tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1993 tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ CHIKE, jẹ́ akọrin, òǹkọ̀wẹ́, akọrinsílẹ̀ àti òṣèré orílẹ̀-èdè Naijiria. Chike jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn akópa nínú ìdíje àwọn Akọrin Project Fame West Africa lẹ́yín ìdíje yìí ni ó gba ipò kejì ni àṣekágbá ìdíje The Voice Nigeria.[1] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣèré fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí ó kópa nínú fíìmù Àgbéléwò BATTLEGROUND èyí tí ó wà lójú ìwòran African Magic inú eré-oníṣe àgbéléwò yìí ni Chike tí ṣe ẹ̀dá ìtàn tí a mọ sí Mayowa.[2]
Chike jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Onitsha, ní Ìpínlẹ̀ Anámbra, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí rẹ̀ bí.
Ipa pàtàkì ni ìdílé Chike kó nínú ìpinnu rẹ̀ láti di olórin.[3] Ó gboyè ẹ̀kọ́ ní Covenant University nínú Computer Engineering[4]
Chike kópa nínú ìdíje project fame, ó tiraka láti wọ ipò kẹwàá.[5]
Chike tún kópa nínú ìdíje The Voice of Nigeria. Ó sì gba ipò kejì.[6][7]
Lẹ́yìn ìdíje The Voice Nigeria níbi tí ó ti gba ipò kejì lẹ́yìn àṣekágbá ìdíje náà. Òun àti àwọn tí ó dé ipile ẹlẹ́ni mẹ́wàá ni wọ́n gbà wò ilé ìṣe onídárayá universal republic. Ó ṣe àgbéjáde orin àkọ́kọ́ FANCY U ni December 2016 lábẹ́ akoso Universal Republic. Chike jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn aṣojú fún Airtel Nigeria pẹ̀lú àwọn méje tí ó dé ipile ẹlẹ́ni mẹsan-án.[8]
Ní ọdún 2017, chike bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣèré fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí ó kópa nínú fíìmù àgbéléwò BATTLEGROUND èyí tí ó wà lójú ìwòran African Magic.[9] Nínú fíìmù àgbéléwò yìí ni Chike tí ṣe àgbéjáde ìwà ẹ̀dá ìtàn Mayowa Badmus. Ní November 2017, Chike kúrò ní Universal Republic láti dá dúró. Ní oṣú kejí, ọdún 2018, ó gbé orin àdákọ rẹ̀ jáde tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Beautiful People"[10]
2020
Ní ọdún 2020, Chike ṣe àgbéjáde àkójọpọ̀ orin mẹ́rìnlá nígbà tí wọ́n gbà á gẹ́gẹ́ bí àlejò pàtàkì ni ètò àgbéléwò big brother lásìkò kónílé-ó-gbélé.
Year | Award | Category | Recipient | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2021 | Net Honours | Most Played RnB Song | "Running to You" (featuring Simi)|style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | [11] |
|url-status=
ignored (help)