Cleopatra Koheirwe | |
---|---|
Born | 15 Oṣù Kínní 1982 |
Show | Mid-Morning Magazine |
Station(s) | Radiocity 97Fm |
Time slot | 10am – 3pm |
Style | Music, celebrity gossip, news |
Country | Uganda |
Orílẹ̀-èdè | Ugandan |
Ẹ̀kọ́ | |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1999–present |
Àwọn ọmọ | 1 |
Cleopatra Koheirwe jẹ́ òṣèré, olórin àti akọ̀wé lórílẹ̀-èdè Uganda. Ó kópa nínú eré The Last King of Scotland gẹ́gẹ́bí Joy ní ọdún 2006. Ó kópa nínú eré Sense8 lóri Netflix.[1][2][3]. Ó ko ipa Ebony nínú eré Reflections èyí tí Nana Kagga ṣe adarí rẹ̀[4][5]. Ó darapọ̀ mọ́ StarTimes Uganda ní oṣù kẹfà ọdún 2019 bí ìkan lára àwọn adarí wọn.[6][7][8]
Ní ọdún 2001, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ oníjó àti olórin Obsession[9], ó sì wá níbẹ̀ títí di oṣù kẹta ọdún 2007[10]. Ní ọdún 2010, ó kọ orin Ngamba[11]. Cleopatra bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbóhùnsáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú 91.3 Capital Fm níbi tí ó tí ṣe atọ́kun ètò Drive Time Show. Ní ọdún 2013, ó ṣe atọ́kun ètò fún U-Request show pẹ̀lú Radiocity 97Fm[12][13]. Ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2013, òun àti Flavia Tumusiimr àti Juliana Kanyomozi ṣe adájọ́ fún ìdíje orin ti Tusker Project Fame ní Kampala.[14][15][16] Cleopatra tí kópa nínú orísìírísìí eré bíi State Research Bureau[17], Sense8[18], Changes, Be the judge ài Yogera. Ní ọdún 2012, Reach a Hand mu láti sọ̀rọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ ni àwọn ilé ẹ̀kọ́[19][20]. Ní ọdún 2010, nígbà tí wọ́n fẹ́ gbé eré Changes apá kejì kalẹ̀, òun àti Nick Mutuma, Pierra Makena, Níní Wacera àti Patricia Kihoro lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Rob Mellor Studios ní Atlanta láti kẹ́kọ̀ọ́ eré ṣíṣe dáadáa.[21]
Wọ́n bí Cleopatra sí ìdílé Jocelyn Twinesanyu àti Anthony Abamwikirize ní ọdún 1982. Ó bí ọmọ bìnrin ní ọjọ́ kẹjìlélógún oṣù kìíní ọdún 2014 fún ọkọ rẹ̀ Lwanda Jawar.[22][23][24]
2019 | Kyaddala | Rahu Counselor | A Reach a Hand Uganda and Emmanuel Ikubese Films production on NBS |
2018 | #Family | Leah | Nabwiso Films TV series. |
Mela | Naava Katende | Savannah MOON Web Series | |
27 Guns | Alice Kaboyo | Natasha Museveni Directed film | |
2017 | Reflections | Ebony | Upcoming TV series created and directed by Nana Kagga Macpherson |
2016 | Sense8 | Mother | TV series created & directed by The Wachowskis |
2013 | Kona | Jakki | Kenyan telenovela [25] |
2011 | State Research Bureau | Faith Katushabe | supporting role |
Yogera | Hope/ G | double lead | |
2010 | Be the Judge | Lucy Mango | a Kenyan local TV series |
2008-10 | Changes | Nanziri Mayanja | a Kenyan DSTV series in seasons 1 & 2 in a supporting role |
2006 | The Last King of Scotland | Joy | supporting role |
Year | Award | Category | Esi |
---|---|---|---|
2013 | RTV Awards | Best Newcomer female radio presenter | Yàán |
2013 | Nile Diaspora's International Film Festival (NDIFF) | Outstanding Actress Honoree Award | Gbàá |
2013 | Radio & Television Academy Awards (RTVAA) Uganda | Best Late Afternoon Show-English (The Jam on Radiocity 97Fm) | Gbàá |
2013 | Buzz Teeniez Awards | Teeniez Role Model | Yàán[26] |
2012 | Super Talent Awards | Most Gifted Actress | Yàán |
2012 | Pearl International Film Festival Awards (PIFFA) Uganda | Best Supporting Actress (S.R.B) | Yàán |
2011 | Kalasha Film & Television Awards, Kenya | Best Actress in a TV Drama (Be the Judge) | Yàán[27] |
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)