Code of Silence

Code of Silence
Fáìlì:Code of Silence (2015).jpg
AdaríEmem Isong
Òǹkọ̀wéBola Aduwo
Àwọn òṣèréMakida Moka, Patience Ozokwor, Ini Edo and Omoni Oboli
Déètì àgbéjáde
  • Oṣù Kẹjọ 8, 2015 (2015-08-08) (Lagos)
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish

Code of Silence jẹ́ eré oníṣẹ́ tí Bola Aduwo kọ tí òṣèré olùgbéré-jáde Emem Isong gbé jáde ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní 2015. Royal Art Art Academy ati Nollywood Workshop fọwọ́sowọ́pọ̀ gbé jáde. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Makida Moka, ẹni tí ó jẹ́ olú-ẹ̀dá ìtàn tí ó kópa gẹ́gẹ́ bí Adanma . Eré yí da lé ìtako Ìwà ìfipá báni lò pọ̀ ati ọ̀nà abáyọ sí ìwà yí pàá pàá jùlọ àwọn tí wọ́n ti lùgbàdì rẹ̀ rí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Agbékalẹ̀ eré náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adanma tí ó jẹ́ olú ẹ̀dá ìtàn tí ó jẹ́ ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ imọ ìṣègùn, ni olóṣèlú àdúgbò àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ fipá bá ní aṣepọ̀ nígbà tí ó ń bọ̀ láti ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ wá sílé. Nígbà tí ó dé ilé, ó ṣalàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si, amọ́ àwọ òbí rẹ̀ gbàá níyànjú láti máṣe sọ ohunkóhun látàrí àìlówó lọ́wọ́ wọn, ẹ̀rù sì tún ń bá wọ́n láti fẹjọ́ sun fún àwọn agbófinró pẹ́lú. [1] Ìfipá-báni lòpọ̀ yí jẹ́ kí Adanma ó ní ìpèníjà orísirṣi tí ó sì ń ṣakóbá fún ìgbésí ayé rẹ̀. [2]

Àwọn ẹ̀dá ìtàn eré náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí wọ́n ṣe gbé eré náà jáde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ilé iṣẹ́ agbéré-jáde méjì ni wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ gbé eré náà jáde. Emem Ìsinmi sọ wípé oun gbà láti kópa nínú eré náà nítorí ila tí oun ń kó nípa ìpolongo tako ìwà ìfipá-báni lòpọ̀, nítorí rẹ̀ ni oun sì ṣe ke eré náà jáde pẹ̀lú láti fi da àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ pàá pàá jùlọ àwọn tí wọ́n bá lùgbàdì ìwà buruku náà kí wọ́n lè Mọ bí a ṣe ń ke gbàjarè síta nígbà tí wọ́n bá hu irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀ sí wọn. Oun sì gbìyànjú láti bá àwọn eda ìtàn inú eré náà ṣiṣẹ́ pọ̀ nítorí wípé oun ti bá wọn ṣiṣẹ́ ri, wọ́n sì lè ṣe ipa tí wọ́n bá fún wọn dàra dára"[2]. Wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípéMakida Moka ni ó ń sunkún lẹ́yìn tí ó ti kópa nínú abala tí ó ti yìnbọn tán, èyí fi hàn bí iṣẹ́ náà ṣe mú u lọ́kàn sí. [3]

Bí àwọn ènìyàn ṣe gba eré náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́ gbé eré ye jáde ní ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kẹjọ ọdún 2015 ní Silverbird GalleriaVictoria Island ní ìlú Èkó.[2] Ẹnìkan sọ wípé eré náà lè mú kí àwọn tí wọ́n ti farakásá ìwà ìfipá bá ni lòpoọ̀ ó pinu láti má ṣe sọ̀rọ̀ síta mọ́ látàrí ohun tí àwọn ènìyàn yóò ma sọ nípa wọn [4]

Àwọn itọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Movie starring Desmond Elliot, Ini Edo, Patience Ozokwor to hit cinemas in August". Pulse. 27 August 2015. Archived from the original on 22 November 2022. Retrieved 22 September 2016. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Emem Isong makes case for rape victims in ‘Code of Silence’". Vanguard. 15 August 2016. Retrieved 22 September 2016. 
  3. "Being short has worked for me – Makida Moka". Punch. 14 February 2016. Retrieved 22 September 2016. 
  4. Kan, Toni (17 August 2015). "‘Code of Silence’ tackles rape…with doses of humour – By Toni Kan". Nigeria Entertainment Today. Archived from the original on 18 August 2015. Retrieved 22 September 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)