"Dami Duro" | ||||
---|---|---|---|---|
Fáìlì:Dami Duro cover.jpg | ||||
Single by Davido | ||||
from the album Omo Baba Olowo | ||||
Released | Oṣù Kẹ̀wá 30, 2011[1] | |||
Recorded | 2011 | |||
Genre | Afropop | |||
Length | Àdàkọ:Duration | |||
Label | HKN Music | |||
Songwriter(s) | David Adeleke | |||
Producer(s) |
| |||
Davido singles chronology | ||||
| ||||
Àdàkọ:External music video |
"Dami Duro" jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin Davido. Wọ́n gbe jáde gẹ́gẹ́ bí i orin àdákọ kejì láti inú àwo-orin Davido, ìyẹn Omo Baba Olowo (2012).[2] Ó wà nípò kìíní lóri àtẹ orin àtòjọ orin mẹ́wàá tó dára jù lọ ti Gold Myne, ní ọdún 2012, tí ó sì wà ṣíwájú orin Iyanya, ìyẹn "Kukere".[3] "Dami Duro" gba àmì-ẹ̀ye Hottest Single of the Year ní Nigeria Entertainment Awards, ní ọdún 2012 .[4] Wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ Best Pop Single àti Song of the Year ní The Headies, ti ọdún 2012.[5] Fídíò orin náà gba àmì-ẹ̀yẹ Most Gifted Newcomer Video of the Year, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n yàn án fún Most Gifted Dance Video of the Year ní Channel O Music Video Awards, ti ọdún 2012 .[6][7] Bákan náà, wọ́n yan fídíò orin náà fún Best African Act Video ní 4Syte TV Music Video Awards, ní ọdún 2012 .[8] Davido gba àmì-ẹ̀yẹ Best Video tí ó tí ọwọ́ olórin tuntun wá ní Nigeria Music Video Awards fún "Dami Duro", ní ọdún 2012.[9]
Àtúnkọ orin "Dami Duro" ṣàfihàn olórin ilẹ̀ Senegal kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akon. Níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú Blue Revolution Entertainment ní Miami, Davido sọ ọ́ di mímọ̀ pé àtúnkọ orin "Dami Duro" jẹ́ èyí tí wọ́n gbà sílẹ̀ ní oṣù Karùn-ún ọdún 2012.[10][11][12] Òǹkọ orin fún Africa Public ṣọ pé, "Mo fẹ́ràn ẹsẹ tuntun yìí, ó fún orin náà ní gbẹ̀du ọ̀tun, àti pé mi ò lè sọ ní pàtọ́ ohùn tó jẹ́ tí Akon tàbí ti Davido. Yàtọ̀ sí pé àwọn irinṣẹ́ orin lóríṣiríṣi jẹ́ kí ohùn wọn dún bákan náà; Akon gbìyànjú gidi gan-an níbi tó ti sọ èdè Yorùbá."[13]
Fídíò fún orin "Dami Duro" jáde ní ọjó kẹjọ oṣù Kìíní ọdún 2012. Clarence Peters ni olùdarí fídíò náà, ó sì jáde lásìkò ìfẹ̀hónúhàn ti Occupy Nigeria.[14][15]
"Dami Duro" tàn káàkiri àgbáyé. Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ́lẹ̀, ìyẹn Abiola Ajimobi kọ orin náà nígbà tí ó ń gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti University of Ibadan níyànjú.[16] Ní oṣù Kejìlá, ọdún 2013, Davido kọ orin "Dami Duro" níbi ayẹyẹ kan. Wọ́n ṣe ìfẹ̀hónúhàn kan ní Kyadondo Rugby Club ní Kampala, níbi tí Jose Chameleon ti kọ orin. Lásìkò tí olórin náà ń kọ orin, Davido bọ̀wọ̀ fún Nelson Mandela.[17]
Ọdún | Ayẹyẹ ìgbà àmì-ẹ̀yẹ | Àpejúwe àmì-ẹ̀yẹ | Èsì |
---|---|---|---|
2012 | Channel O Music Video Awards | Most Gifted Dance Video of the Year | Wọ́n pèé |
Most Gifted Newcomer Video of the Year | Gbàá | ||
Nigeria Music Video Awards (NMVA) | Best Video By A New Artiste (Live Beats Choice) | Gbàá | |
4Syte TV Music Video Awards | Best African Act Video | Wọ́n pèé | |
Nigeria Entertainment Awards | Hottest Single of the Year | Gbàá | |
The Headies | Best Pop Single | Wọ́n pèé | |
Song of the Year | Wọ́n pèé |
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)