Dolly Rathebe | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Randfontein, South Africa | 2 Oṣù Kẹrin 1928
Aláìsí | 16 September 2004 | (ọmọ ọdún 76)
Occupation(s) | Singer, actress |
Dolly Rathebe (bíi ni ọjọ́ kẹji, oṣù kẹrin ọdún 1928)[1] jẹ́ òṣèré àti olórin ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà. Ó kú ní ọjọ́ kerìndínlógún oṣù kẹsàn-án, ọdún 2004.[2]
Ní ọdún 1984, nígbà tí ó kọrin ní bi tí àwọn èèyàn ti ń ṣe fàájì ni ilu Johannesburg,[3] ní àwọn kan lọ bá wípé kí ó wà ṣiṣẹ́ lọdọ wọn, kò pé díè tí ó wà lọ́dọ̀ wọn ní o di gbajúmọ̀ láàrin ìlú.[4] Rathebe di gbajúmọ̀ ni ọdún 1949, nígbà tí ó lọ kọrin nínú eré Jim Comes to Jo'burg. Nígbà tí egbe olórin Alf Herbert's African Jazz and Variety Show bẹ́rẹ̀ ni ọdún 1954, Rathebe darapọ̀ mọ́ wọn, ó sì má ń bá wọn kọrin. Ní ọdún 2001, Rathebe gba ẹ̀bùn Lifetime Achievement Award níbi ayẹyẹ South African Music Awards. Ní ọdún 2004, ó gbà àmì ẹ́yẹ Order of Ikhamanga fún ipá rìbìtìti ó ti kó nínú orin kíkọ.