Michael Collins Ajereh (tí a bí ní ọjọ́ 26, oṣù kọkànlá, ọdún 1982), tí a mọ̀ mọ́ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Don Jazzy,jẹ́ aṣàgbéjáde rẹ́kọ́ọ̀dù ní Nàìjíríà , aṣojú fún àwọn ilé-iṣẹ́ , onímọ̀ ẹ̀rọ ohùn , ọ̀gá ilé-iṣẹ́ orin, olórin , olókòwò, olùsọdimímọ̀ àti adẹ́rínpòṣónú. Òun ni olùdásílẹ̀ àti ọ̀gá ilé iṣẹ́ Mavin Records.[1] Don Jazzy jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n ni ilé-iṣẹ́ orin tí ó ti kógbá wọlé Mo' Hits Records pẹ̀lú Dbanj. Àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin ni D'Prince.
A bí Don Jazzy gẹ́gẹ́ bí Micheal Collins Ajereh ní Umuahia, Abia State, ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá, ọdún 1982,[2] ọmọ ọkùnrin tí Collins Enebeli Ajereh àti Mrs Ajereh bí . Bàbá rẹ̀ wá láti Isoko ní Delta State. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Ọmọọba Igbo láti Ìpínlẹ̀ Abia nígbà tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ará Isoko .[3]D'Prince ni àbílẹ́yìn Don Jazzy lọ́kùnrin. Ìdílé Don Jazzy kó lọ sí Ajegunle, Èkó Ní ibi tí wọ́n ti tọ́ Don Jazzy.[4]
Ìdílé Ajereh kó lọ sí Ajegunle, Èkó, níbi tí wọ́n ti tọ́ Don Jazzy .[5] Ó kàwé ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga takọtabo, Federal Government College Lagos. Ìfẹ́ tí Don Jazzy ní sí orin bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà kékeré, nígbà tí ó sì pé ọdún méjìlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí ni ta gìtá, ó sì ń tẹ dùùrù. Ó tún kọ́ nípa àwọn ohun èlò orin tiwantiwa àti àwọn èyí tí ó ní okùn. Don Jazzy lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ìmójútó okòwò ní Yunifásítì Ambrose Alli , Ekpoma, Ìpínlẹ̀ Ẹdó.
Ní ọdún 2000, ìbátan Jazzy pè é kí ó wá lu ìlù fún ìjọ agbègbè ní London, èyí sì jẹ́ ìrìn àjò kìíní rẹ̀ lọ sí London.[6] Don Jazzy rí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i abániṣọ́lé ní McDonald's. Ó tẹ̀ síwájú nínú ìfẹ́ rẹ̀ sí orin , ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Solek, JJC Skillz, Kas, Jesse Jagz, The 419 Squad ati D'banj.
Don Jazzy fẹ́ Michelle Jackson ní ọdún 2003. Ó jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé àwọn ní àwọn ìṣòro nípasẹ̀ bí òun ṣe jẹ́ alákínkanjú ènìyàn tí ó ń lé iṣẹ́, wọ́n sì pínyà lẹ́yìn ọdún méjì tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n ṣá, kò sí nínú ètò rẹ̀ láti fẹ́ ìyàwó mìíràn ní kíákíá nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ pé ìfẹ́ àti ìfinjì rẹ̀ fún orin lè tún dá ègbodò fún ìfẹ́ ẹlòmíràn sí í. [7][8]
Ní 2004, Don Jazzy fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú D'banj láti dá Mo' Hits Records sílẹ̀ . Ní ọdún méjì tí ó tẹ̀le , Don Jazzy gbé àwo No Long Thing àti Rundown/Funk You Up jáde . "Thunder fire" you náà sì ti bẹ̀rẹ̀ ní àkókò náà . Ní àkókò yìí , Don Jazzy bẹ̀rẹ̀ ìfarahàn tí ó jẹ́ tirẹ̀ nìkan, "It's Don Jazzy Again!"
Ní ọdún 2008, Don Jazzy náà ní àfikún nínú àgbéjáde The Entertainer láti ọwọ́ D'Banj. Ó tún ní àfikún nínú àgbéjáde àwo Wande Coal Mushin 2 MoHits, àwo tí wọ́n ṣe àpèjúwe gẹ́gẹ́ bí i ọkàn lára àwọn àwo ti ó dáńtọ́ jù tí ó ti jáde láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[9]
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àfikún Don Jazzy kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí i olórin, ó máa ń ṣe elégbè fún àwọn olórin tí ó gbé jáde . Àwọn iṣẹ́ tí ó ti ṣe ni ègbè fún àwọn olórin bí i D'banj Sauce Kid, Dr SID, Ikechukwu, Kween, D'Prince, Jay-Z. Don Jazzy ṣe ègbè fún orin Kanye West, "lift up" pẹ̀lú Beyoncé nínú àwo "Watch the Throne".
Ní ọdún 2011, Kanye West gba Don Jazzy síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i aṣàgbéjáde ohùn ní. Don Jazzy ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jay-Z àti Kanye West lórí àgbéjáde "lift up" tí wọ́n pe Beyoncé sí nínú àwo "Watch the Throne" tí wọ́n fi síta ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹjọ, ọdún 2011.
Ní oṣù kẹta, ọdún 2012, Don Jazzy àti D'Banj fìdí ìpínyà wọn múlẹ̀ pẹ̀lú ìdí ìyàtọ̀ nínú iṣẹ́-ọnà .[10]
Ní ọjọ́ keje, oṣù karùn-ún, ọdún 2012, Don Jazzy kéde ilé-iṣẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tuntun, Mavin Records. Ó ní , "Mo rí Mavin Records pé yóò jẹ́ ilé agbára orin ní Áfíríkà ní ìwọ̀nba àsìkò tí ó kéré jù tí ó ṣeéṣe ."[11] Ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù karùn-ún, ọdún 2012, ó gbé àwo tí ó ní àwọn olórin tí wọ́n tọwọ́bọ̀wé pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ orin rẹ̀ jáde. Àwọn orin tí wọ́n wà lórí àwo náà ni: IAmarachi, Forever, Oma Ga, Take Banana and Chocolate, YOLO àti orin I'm a MAVIN. Mavin gba àwọn olórin bí i, Tiwa Savage. Don jazzy gbé ìtagbà ibánidọ́ọ̀rẹ̀ tí ó pè ní "Marvin League" dìde láti gbé ilé-iṣẹ́ rẹ̀ jáde àti láti polówó ilé-iṣẹ́ orin rẹ̀.[12]
Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kọkànlá, ọdún 2013, Ajereh ní èdè àìyedè pẹ̀lú olórin rẹ̀ kan, Wande Coal tí ó fi ilé-iṣẹ́ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ méjì.[13]
Ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2014, Ajereh gbé orin ajàfẹ́tọ̀ọ́ àwùjọ Nàìjíríà kan jáde pẹ̀lú Reekado Banks àti Di'Ja tí wọ́n pè ní Arise.[14]
Níbi tí wọ́n ti ń gba àmì ẹ̀yẹ Headies Awards 2015, Ajereh jiyàn pẹ̀lú Olamide. Àwọn méjèèjì jiyàn lórí ẹni tí ó yẹ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ "Next Rated". Ó bọ́ lọ́wọ́ Lil Kesh ti YBNL records lọ sí ọwọ́ Reekado Banks, tí ó jẹ́ olórin ní abẹ́ Ajereh'. Ẹni tí ó gba àmì ẹ̀yẹ náà gba ọkọ̀ bọ̀gìnnì. Àwọn apá méjèèjì ni wọ́n fi ẹ̀bẹ̀ má bínú léde lẹ́yìn náà.[15][16]
Lẹ́yìn ìpínyà Reekado Banks kúrò ní ilé-iṣẹ́ Mavin Records label, Don Jazzy sọ pé ó ṣì jẹ́ ọ̀kan lára ẹbí náà, ó sì gba èróńgbà àṣeyọrí fún un bí ó ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àsìkò tí ó lò pẹ̀lú Mavin Records.[17]
Ní ọdún 2019, ó gba Rema, ó sì tẹ̀ síwájú láti gba Ayra Starr ní ọdún 2020 sí ilé-iṣẹ́ orin Mavins Record Label. Ní ọdún 2021, ó kéde olórin tuntun, Magixx.[18]