Sumonu Oladele Giwa | |
---|---|
Fáìlì:Dele Giwa Portrait.jpg | |
Ọjọ́ìbí | 16 March 1947 Ile-Ife, British Nigeria |
Aláìsí | 19 October 1986 (Age 39) Ikeja, Lagos State, Nigeria |
Cause of death | Mail bomb explosion |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ẹ̀kọ́ | Brooklyn College, New York City Fordham University |
Iṣẹ́ | Journalist,Editor And a Publisher. |
Gbajúmọ̀ fún | Newswatch |
Notable work | Founder of Newswatch magazine |
Olólùfẹ́ | Florence Ita Giwa (1980s; divorced) Olufunmilayo Olaniyan (1984-1986; his death) |
Àwọn ọmọ | 5 |
Dele Giwa tí abísọ rẹ̀ ń jẹ́ Sùmọ́nù Ọládélé Baines Giwa jẹ́ ọmọ prílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí won bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta ọdún 1947, tí ó sì papò dà ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹwá ọdún 1986. (16 March 1947 – 19 October 1986) jẹ́ oníṣẹ́ ìwé ìròyìn àti olóòtú ìwé ìròyìn ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Newswatch.
Sùmọ́nù Ọládélé Baines Giwa won bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta ọdún 1947, tí ó sì papò dà ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹwá ọdún 1986. (16 March 1947 ) ni wọ́n bí sínú ẹbí ìkan nínú àwọn òṣìṣẹ́ l'áàfin Ọba Adesoji Aderemi nígbà ayé rẹ̀.
Délé l9 sí ilé-ẹ̀kọ́ L.A tí ó wà ní Làgèrè ní ìlú Ilé-Ifẹ̀. Ó sì wọ ilé-ẹ̀kọ́ ti Odùduwà College ní Ilé-Ifẹ̀ nígbà tí bàbá rẹ̀ ríṣẹ́ sí ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alágbàfọ̀.[1] Délé tún lọ sílé ẹ̀kọ́ àgbà ní ìlú Amẹ́ríkà tí ó sì kẹ́kọ́ gboyè BA nínú ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ulé-ẹ̀kọ́ Brooklyn College ní ọdún 1977. Ó tún sì tún lọ sílé ẹ̀kọ́ Fordham University láti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè siwájú si. Ó ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn ilẹ̀ Amerika tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ The New York Times gẹ́gẹ́ bí amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn náà fún odidi ọdún mẹ́rin gbáko ṣáájú kí ó tó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti sìṣẹ́ nílé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Daily Times tí ó wà ní ìlú Èkó.[2]
Délé Gíwá, Ray Ekpu, Dan Agbese ati Yakubu Mohammed ni wọ́n jọ pawọ́pọ̀ dá ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn Newswatch [3] ní ọdún 1984, wọ́n sì gbé àpilẹ̀kọ akọ́kọ́ jáde ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kíní ọdún 1985, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ń pin ká ní oṣù kíní. [4] Délé gbé iṣẹ́ ìmọ̀ ìròyìn àti ìkóroyìn jọ jáde ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ṣíṣàfikún ìgboyà àti ìtọpinpin nínú iṣẹ́ ìròyìn nígbà ayé rẹ̀.[5] Ní àsìkò ìjọba Ààrẹ apàṣẹ wàá lábẹ́ ìjọba ológun Ibrahim Babangida tí ó gba ìjọba ní inú oṣù kẹjọ ọdún 1985. Délé gbé àwòrán ojú Ààrẹ náà sí ojú ewé akọ́kọ́ ìwé ìròyìn náà ní ẹ̀mẹ́rin tí ó sì tún ń fẹnu àbùkù sọ tẹni bá ro wípé òun yóò ma da ìjọba Ààrẹ Babangida rà.[6] Nígbẹ̀yìn, ìwé ìròyìn Newswatch gbójú agan sí Ààrẹ náà lásìkò ìjọba rẹ̀.[7]
Délé Gíwá fẹ́ ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí ó jẹ́ oníṣẹ́ ìlera ní ọdún 1974.[2] Ó fẹ́ ìyàwó kejì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Florence Ita Giwa, amọ́ ìgbéyàwó wọn kò ju lò ju oṣù mẹ́wá lọ kí ó tó túká. Lẹ́yìn náà ó tún ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú arabìnrin Olufunmilayo Olaniyan ní ọjọ́ kẹwá oṣù keje ọdún 1984, tí wọ́n sì jọ wà papọ̀ títí di àsìkò ikú rẹ̀ ní ọdún 1986.[8] Ìyá rẹ̀ tó bi àti ọmọ rẹ̀ ni wọ́n gbẹ̀yìn rẹ̀.[9][10]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
|url-status=
ignored (help)