Eedris Abdulkareem | |
---|---|
![]() Eedris Abdulkareem at the endSARS protest in Lagos, Nigeria | |
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Eedris Turayo Abdulkareem Ajenifuja |
Ọjọ́ìbí | 24 Oṣù Kejìlá 1974 Kano, Nigeria |
Ìbẹ̀rẹ̀ | Osun State, Nigeria |
Irú orin | R&B, African hip hop |
Occupation(s) | Rapper, farmer |
Years active | 1996–present |
Labels | Kennis Music (? – 2005) La Kreem Music (2005 – Present) |
Eedris Turayo Abdulkareem Ajenifuja (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kejìlá, ọdún 1974) tí gbogbo ayé mọ̀ sí Eedris Abdulkareem, jẹ́ olórin ilẹ̀ Naijiria tó máa ń kọ orin hip-hop, RnB àti Afrobeat, ó tún máa ń kọ orin kalẹ̀.
Ìdíle olórogún ni a bí Eedris Turayo Abdulkareem Ajenifuja sí ní ìpínlẹ̀ Kano, ní orílẹ̀-èdè Naijiria. Ìlú Ilesha, ní ipinle Osun ni bàbá rẹ̀ ti wá, ìyá rẹ̀ sì wá láti ipinle Ogun, tí ó wà ní apá Gúúsù ilẹ̀ Naijiria, àmọ́ ó yan Ipinle Kano gẹ́gé bíi ìlú tó ti wá.[1]