Fausat Balogun | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Fausat Balogun 13 Oṣù Kejì 1959 Ifelodun, Kwara State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Madam ṣajẹ |
Iṣẹ́ | Film actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1975–present |
Olólùfẹ́ | Rafiu Balógun |
Fausat Balogun tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Madam ṣajẹ,[1] ní wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún 1959 (February 13th, 1959) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá ni Madam ṣajẹ tí gbajúmọ̀. [2][3] Gbajúmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ó kópa ère àwàdà lorí tẹlifíṣàn kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀rín kèékèé. Nínú eré yìí ni ó ti gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Madam ṣajẹ lọ́dún 1990. Lẹ́yìn èyí, Fausat Balógun tí kópa nínú eré sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rin lọ.[1][4]
Fausat Balógun fẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rafiu Balógun, Rafiu jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ kí wọ́n tó fẹ́ ara wọn.[1] Nígbà tí ó fi di gbajúmọ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ ti dàgbà. Àkọ́bí rẹ̀ jẹ́ olùdarí fíìmù àgbéléwò, àbígbẹ̀yìn rẹ̀ tó sì jẹ́ obìnrin náà jẹ́ òṣèré fíìmù àgbéléwò.[4]