Funmi Olonisakin

Funmi Olonisakin
Ọjọ́ìbí8 Oṣù Kejì 1965 (1965-02-08) (ọmọ ọdún 59)
Orílẹ̀-èdèBritish Nigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ife Obafemi Awolowo University King's College London
Iṣẹ́Lecturer, Researcher
Websitefunmiolonisakin.com

Funmi Olonisakin (tí a bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejì ọdún 1965) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó jẹ́ onímọ̀ àti ọ̀jọ̀gbọ́n ti leadership peace and conflict ní King's College, ní ìlú London. Ó sì tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n tó dáńtọ́ ní University of Pretoria.[1] Ó jẹ́ olùdásílẹ̀, ó sì tún fìgbà kan jẹ́ adarí African Leadership Centre (ALC), èyí tí wọ́n dá sílẹ̀ lórí ìlànà Pan-Africanism láti kọ́ àwọn adarí àti onímọ̀ ilẹ̀ Afrika ti ìran tó ń bọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò fún ìyípadà ọ̀tun. Olonisakin ni olùdarí ètò ti ALC's Master of Science (MSc) lórí àọn ètò lórí ìṣàkóso, àlàáfíà àti ààbò.[2] Ó jẹ́ olùṣèwádìí ní ẹ̀ka Political Sciences ní University of Pretoria, ó sì tún fìgbà kan jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Andrew Mellon Foundation àti ọmọ-ẹgbẹ́ Geneva Centre for Security Policy (GCSP). Lọ́wọ́lọ́wọ́, wọ́n yàn án ní United Nations Security Council (UNSC) láti jẹ́ olùdámọ̀ràn fún ẹgbẹ́ náà, tó sì tún ṣaàgbéyẹ̀wò UN Peace-building Architecture.[3][4]

Wọ́n bí Funmi (Oluwafunmilayo) Olonisakin [5] sí apá Gúúsù ilẹ̀ London sínú ìdílé àwọn ọmọ Nàìjíríà.[6] Ó gba oyè ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ ní Obafemi Awolowo University, ní Ilé-Ifẹ̀, ní Nàìjíríà, nínú ẹ̀kọ́ Political Science. Ó tẹ̀síwájú láti gboyè ẹ̀kọ́ kejì nínú ẹ̀kọ́ War Studies, ní King's College London. [7]

Àṣàyàn àwọn ìwé-àtẹ̀jáde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìwé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
    • Militancy and Violence in West Africa: Religion, Politics and Radicalization, ed.James Gow, Funmi Olonisakin & Ernst Dijxhoorn. London: Routledge, 2013. ISBN 9780415821377
    • Women and Security Governance in Africa, ed. Funmi Olonisakin & Awino Okech. Oxford: Pambazuka Press, 2011. ISBN 9781906387891ISBN 9781906387891
    • Women, Peace and Security: Translating Policy into Practice, ed. Funmi Olonisakin, Karen Barnes & Eka Ikpe. London: Routledge,2011. ISBN 9780415587976ISBN 9780415587976
    • Security Sector Transformation in Africa, ed. Alan Bryden & Funmi Olonisakin. Munster: Lit Verlag, 2010. ISBN 9783643800718ISBN 9783643800718
    • The Challenges of Security Sector Governance in West Africa, ed. Alan Bryden, Boubacar Ndiaye & Funmi Olonisakin. Munster: Lit Verlag, 2008. ISBN 9783037350218ISBN 9783037350218
    • Peacekeeping in Sierra Leone: The Story of UNAMSIL. Boulder and London: Lynne Reinner, 2008. ISBN 9781588265203ISBN 9781588265203
    • Global Development and Human Security, ed. Robert Picciotto, Funmi Olonisakin & Michael ClarkeNew Brunswick and London: Transaction Publishers, 2007. ISBN 9781412811484ISBN 9781412811484
    • A Handbook of Security Sector Governance in Afric], ed. Nicole Ball & Kayode Fayemi. London: Centre for Democracy and Development, 2004.
    • Reinventing Peacekeeping in Africa: Conceptual and Legal Issues in the ECOMOG Operations. The Hague: Kluwer Law International, 2000. ISBN 9789041113214ISBN 9789041113214
    • Engaging Sierra Leone. London: Centre for Democracy and Development, 2000. ISBN 9781902296081ISBN 9781902296081
    • Peacekeepers, Politicians and Warlords, by Abiodun Alao, Funmi Olonisakin & John Mackinlay Tokyo: United Nations University Press, 1999. ISBN 9789280810318ISBN 9789280810318

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Professor 'Funmi Olonisakin". www.kcl.ac.uk (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-10. 
  2. "Adjunct Faculty", African Leadership Centre. Retrieved 23 June 2016.
  3. "Secretary-General Nominates Advisory Group of Experts on Review of Peacebuilding Architecture", United Nations | Meetings Coverage and Press Releases, 22 January 2015. Retrieved 10 August 2015.
  4. "Dr. ‘Funmi Olonisakin appointed to United Nations Advisory Group of Experts", Carnegie Corporation, 30 January 2015. Retrieved 24 June 2016.
  5. "‘Funmi (Oluwafunmilayo) Olonisakin", African Feminist Forum. Retrieved 24 June 2016.
  6. First Black Woman professor at King's College delivers inaugural lesson, Ghana News Agency, 20 June 2018
  7. "Dr. Funmi Olonisakin, Director of the African Leadership Centre" Archived 2016-08-18 at the Wayback Machine., Tana Forum. Retrieved 24 June 2016.