Glenrose Xaba

Glenrose Xaba tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kẹẹ̀wá ọdún 1994 jẹ́ ọmọ orílẹ̀ ède South Africa tí ó n sáré ọlọ́nà jínjìn. Ó parí ìdíje ti ipò àgbà fún àwọn obìrin ní IAAF World Cross Country Championships ní ọdún 2019 tí ó wáyé ní Aarhus, Denmark, [1] Ó parí ní ipò kẹtàdínláàádọ́rin.

Ó kópa nínú ìdíje àwọn obìnrin kéékèèké ti IAAF World Cross Country Championships ti ọdún 2013 tí ó wáyé ní Bydgoszcz, Pólándì.

Ní ọdún 2015, ó gba ààmì-ẹ̀yẹ fàdákà níbi eré sísá mítà 10,000 ti àwọn obìnrin níbi ìdíje South African Athletics Championship tí ó wáyé ní Stellenbosch, South Africa. Ó tún gba ààmì-ẹ̀yẹ idẹ níbi ayẹyẹ eré mita ẹgbẹ̀rún-máàrún ti àwọn obìnrin. Ní ọdún 2016, ó kópa nínú ìdíje mita ẹgbẹ̀rún-mẹ̀wá ti àwọn obìnrin níbi African Championship tí ó wáyé ní Durban, South Africa.

Ní ọdún 2017, ó kópa nínú ìdíje eré sísá àwọn obìnrin àgbà níbi IAAF World Cross Country Championships tí ó wáyé ní Kampala, Uganda. Ó parí ní ipò kẹrìnlélọ́gọ́ta. Ní ọdún 2018, ó kópa nínú ìdíje àwọn obìnrin àgbà níbi African Cross Country Championship tí ó wáyé ní Chlef orílẹ̀ ède Algeria.

Kò gbéwọ̀n láti kópa fún2020 Summer Olympics ní Tokyo, Japan torí pé ó ṣeléṣe.[2]

Àwọn àṣeyọrí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Representing  Gúúsù Áfríkà
2020 World Championships (HM) Gdynia, Poland 16th Half marathon 1:09:26

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Glenrose Xaba níbi World Athletics

Àdàkọ:Authority control