Gold Coast Lounge | |
---|---|
![]() Poster | |
Adarí | Pascal Aka |
Àwọn òṣèré | Adjetey Anang Fred Nii Amugi Akofa Edjeani Asiedu Alphonse Menyo Cina Soul Zynnell Zuh |
Orílẹ̀-èdè | Ghana |
Èdè | English |
Gold Coast Lounge jẹ́ fíìmù ti orílẹ̀-èdè Ghana tó jáde ní ọdún 2020, èyí tí Pascal Aka ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ tí ó sì darí fíìmù ọ̀hún. Àwọn òṣèré tó kópa nínú fíìmù náà ni Alphonse Menyo, Adjetey Anang, Zynnell Zuh, Raquel.[1][2][3]
Ilé-iṣẹ́ Gold Coast Lounge, èyí tí John Donkor tó jẹ́ ọ̀daràn ń darí jẹ́ agbègbè kan tí àwọn ọ̀daràn máa ń pọ̀ sí jù. Ìjọba tuntun sì pinnu láti ti ibẹ̀ pa. Lásìkò yìí, Donkor fúnra ẹ̀ wà ní ẹ̀wọ̀n, èyí sì mú kí àwọn ọmọọṣẹ́ Donkor máa ṣamójútó iṣẹ́ náà, ìyẹn Daniel àti Wisdom.
Àwọn méjèèjì ni Donkor gbà tọ́ láti ìgbà tí wọ́n wà ní ọmọ kékeré. Daniel àti Wisdom bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe orogún ara wọn nítorí ipò olùdarí iṣẹ́ yìí. Ìṣorogún yìí wá pọ̀ si lẹ́yìn tí Donkor fi ìdí ẹ̀ lélẹ̀ pé Daniel ni ó máa jogún iṣẹ́ òun.
Lẹ́yìn tí wọ́n pa olórí wọn, èyí tó dàgbà jù lọ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàkóso iṣẹ́, èyí sì fa ìwádìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ìjọba.
Ní ọdún 2019, fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́jọ ní Ghana Movie Award, bẹ́ẹ̀ sì ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́fà ní Golden Movie Awards ní ọdún 2020.[7]
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)