Habiba Nosheen jẹ́ oníròyìn ìwádìí.[1] Eré rẹ̀, outlawed in Pakistan tí wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ ní ọdún fíìmù jẹ́ ọ̀kan nínù àwọn tí wọ́n fakọyọ gẹ́gẹ́ bí Los Angeles times ṣe gbee jáde. Fíìmù náà oní àsìkò gbọgbọrọ di gbígbé jáde ní PBS Frontline.
Àkọsílẹ orí rédíò ní ọdún 2012, "What Happened at Dos Erres?" tí wọ́n gbé sí orí affairs This American Life tí The New Yorker sì gbà pé àlọ́ tí ó yege ní". Nosheen gba àwọn àmì ẹ̀yẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìròyìn rẹ̀ tí àmì ẹ̀yẹ Peabody àti three Emmy sì pẹ̀lú.
Láàrin 2017-2019, Nosheen jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ olóòtú ní ilé iṣẹ́ amóunmáwòrán CBC tí ẹ̀ka new magazine series, The fifth Estate.[2] Òun ni àkọ́kọ́ ẹni tí kìí ṣe aláwọ̀ funfun tí ó di ipò amúgbálẹ́gbẹ̀ olóòtú náà mú làti nkán bíi ọgbọ́n ọdún.
Ní ọdún 2022 ṣe àgbéjáde ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àgbéléwò òní ìwádìí alápá mẹ́jọ pẹ̀lú Spotify àti ilé iṣẹ́ ìròyìn Gimlet tí wọn pè ní Ẹ̀sùn: àwátì Nuseiba Hasan. Ètò náà wáyé fún odún meta nítorí ọmọ obìrin ara Canada kan tí ó di àwátì láti ọdún 2006 láì sí ẹni tí ó gbúro rẹ̀ rárá.[3]
Wọ́n bí Nosheen ní Lahore, Pakistan. Ẹbí rẹ̀ kó lọ sí Toronto ní Canada ní ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Ó gba ìwé ẹ̀rí gíga kejì (Master's) láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Colombia, ilé ẹ̀kọ́ Ìkó'ròyìnjọ (journalism) àti ìwé ẹ̀rí gíga kejì míràn láti Ilé ẹ̀kọ́ gíga York, Toronto nínú ìmọ̀ nípa Ẹ̀dá Obìnrin. Ó gba ìwé ẹ̀rí gíga àkọkọ́ (Bachelor's degree) ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Toronto. Ó gbọ́ gẹ̀ẹ́sì, Urdu, Hindi and Punjabi dé ojú àmì.
Kíkà-ìròyin rẹ̀ tí jẹyọ ní ọpọ ilé iṣẹ́ ìròyìn ti New York Times, The Washington Post, Time, Glamour, BBC, CBC, PBS, NPR and This American Life wà lára wọn.[4][5][6][7][8][9][10][11]
Àwọn àkọsílẹ̀ Nosheen tí rí ìkúnlọ́wọ́ lati àjọ tí ó ń rí sí fifun ìròyìn oní ìwádìí lówó, àgọ́ Pulitzer lórí ìròyìn ogun, The Nation Institute's Investigative Fund àti ITVS. Ó tí ṣiṣẹ́ olùkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Ìkó'ròyìnjọ Columbia
Ní oṣù kẹta, ọdún 2022 Nosheen ṣe àgbéjáde ìwádìí alápá mẹ́jọ lórí ọ̀rọ̀ ọmọ obìrin Hamiltoni kan kan tí ó di àwátì. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà wáyé ní ilé iṣẹ́ ìròyìn Gimlet. Wọn pè àkórí rẹ̀ ní "Ẹ̀sùn: àwátì Nuseiba Hasan."[12]