Hilda Dokubo | |
---|---|
Dokubo crying while speaking on how hunger affects poor people at the HungerFREE Campaign of ActionAid in 2007 | |
Ọjọ́ìbí | Buguma, Asari-Toru, ìpínlẹ̀ Rivers |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | òṣèrébìnrin |
Hilda Dokubo tí a tún mọ̀ sí Hilda Dokubo Mrakpor jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ àwọn ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti fìgbà kan jẹ́ olùgbaninímọ̀ràn pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ fún Gómìnà àná ìpínlẹ̀ Rivers, Peter Odili.[1][2]
Wọ́n bí ní Hilda Dokubo, tí ó jẹ́ àkọ́bí fún àwọn òbí rẹ̀ ìlú Buguma, ní Asari-Toru, ìpínlẹ̀ Rivers, níbi tí ó ti kàwé àkóbẹ̀rẹ̀ àti sẹ́kọ́ndìrì ní ilé ìwé St Mary State School, lópópónà Aggrey àti Government Girls Secondary School.[3] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gbàwé ẹ̀rí dìgírì àkọ́kọ́ àti ìkejì nínú ìmọ̀ iṣẹ́ Tíátà ní ifáfitì.[3]
Nígbà ìsìnlú, iṣẹ́ àgùnbánirọ̀ ni Dokubo kópa nínú sinimá àgbéléwò àkọ́kọ́ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Evil Passion lọ́dún 1992. Láti ìgbà náà ló ti di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà nínú sinimá àgbéléwò, tí ó sìn ti ṣe olóòtú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìgbò.[4] Lọ́dún 2015, Dokubo gba àmìn ẹ̀yẹ tí Africa Movie Academy fún ipa ẹ̀dá ìtàn tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Stigma. [5]
Fatal
Ọdún | Orúkọ afúnni lámìn-ẹ̀yẹ | Àmín ẹ̀yẹ | Èsì | Àwọn Ìtọ́kasí |
---|---|---|---|---|
2015 | Àmìn ẹ̀yẹ sinimá àgbéléwò Áfíríkà ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá | Òṣèrébìnrin tó dára jùlọ fún amúgbalẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-ẹ̀dá ìtàn | Gbàá | [6] |
Àjọ̀dún ẹlẹ́ẹ̀kejìlá sinimá àgbéléwò àgbáyé tí Àbújá | Òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò tó dára jùlọ | Gbàá | [7] |