Ijakumo | |
---|---|
Adarí | Adebayo Tijani Steve Sodiya |
Olùgbékalẹ̀ | Toyin Abraham |
Òǹkọ̀wé | Kehinde Joseph |
Àwọn òṣèré | Toyin Abraham Kunle Remi Lolade Okusanya Bimbo Akintola Olumide Oworu |
Orin | Abosede Peace |
Ìyàwòrán sinimá | Idowu 'Mr Views' Adedapo |
Olóòtú | Steve Sodiya Agboola Ola'Kazeem |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Toyin Abraham Films Production |
Olùpín | FilmOne Distribution |
Déètì àgbéjáde | 23 December 2022 |
Àkókò | 120 Minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English, Yoruba, Igbo, Hausa |
Owó àrígbàwọlé | ₦278,496,384[1] |
Ijakumo (The Born Again Stripper) jẹ́ fíìmù ajẹmọ́-ìṣiyèméjì ti ọdún 2022, èyí tí Toyin Abraham gbé jáde, tó sì di àgbéléwò ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kejìlá, ọdún 2022.[2] Àwọn tó kópa nínú eré náà ni Toyin Abraham, Kunle Remi, Lolade Okusanya, Bimbo Akintola, Olumide Oworu, Lillian Afegbai àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3] Kehinde Joseph ni olùkọ̀tàn, nígbà tí Adebayo Tijani sì jẹ́ olùdarí.[3]
Ijakumo (The Born Again Stripper) sọ nípa ìtàn Asabi (Toyin Abraham), tó jẹ́ ọmọ oníṣègùn alágbára kan tó ń lépa láti ba ayé olólùẹ́ àtijọ́ rẹ̀ jẹ́, ní ẹni tó ti di pásítọ̀ ńlá kan ní ìlú Èkó, ìyẹn Jide(Kunle Remi) tó yàn án jẹ, tó sì fi í lẹ̀ kó kú. Pastor Jide tí kì í ṣe ènìyàn Ọlọ́rún, àmọ́ tó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ òkùnkùn kan tó máa ń wùwà àìtọ̀. Nínú ìgbìyànjú rẹ̀ láti ba ayé Jide jẹ́, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Sharon(Lolade Okusanya), ẹni tó jẹ́ oníjó-kílọ́ọ̀bù àti akọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì Jide, tó wá ń wá ìṣubú rẹ̀.[4]
Àọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn bí i Gómínà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo Olu, àti àwọn gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn ló farahàn níbi ìṣàfihàn àkọ́kọ́ ti fíìmù yìí. Àwọn ẹlòmìíràn tó farahàn ni Odunlade Adekola, Iyabo Ojo, Lateef Adedimeji àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[5] [6]
Year | Award | Category | Recipient | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2023 | Africa Magic Viewers' Choice Awards | Best Picture Editor | Steve Sodiya | Wọ́n pèé | [7][8] |
Best Sound Editor | Kazeem Agboola | Wọ́n pèé | |||
Best Cinematographer | Idowu Adedapo | Wọ́n pèé |