Ilé isé olùpèsè okò Innoson ti orílè èdè Nàîjíríà, tí eon we àgékúrú rè sí IVM, jé ilé isé tí ó n pèsè orísirísi ohun amurînà gégé bí okò akérò, okò igbafé ní orílè èdè Nàîjíríà.. Ògbéni Innocent Chukwuma ni ó jé olùdásílè tí ó sì n se àmójútó ilé isé náà ní ìlú Nnewi ní ìpínlè Anambra.[1][2]
Ìdá ogórin (70%) àwon èyà ara okò ni wón n pèsè fúnra won lábélé ,[3] nígbà tí wón n kó àwon èyà ara okò tókù wolé láti ilè òkèrè bí ilè Jamaní (Germany), ilè Jàpáànù (Japan) àti ilè Sáínà (China) .
Lára àwon irúfé okò tí wón n se jáde níbè nílé isé IVM ni: okò oníjölòókòó márùún a (five-seaters) Fox, tí ó n lo ìwòn epo (1,5 liter engine) àti èyí tí wón pè ní Umu tí enjìnì rè jé oní jálá epo méjì (2 liter engine) , pèlú okò ayókélé kékeré tí ó n jé Uzo.[4]