Ishaya Bako | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 30 Oṣù Kejìlá 1986 Kaduna |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ | Covenant University, London Film School |
Iṣẹ́ | Nigerian film director and screenwriter |
Gbajúmọ̀ fún | His film Fuelling Poverty |
Notable work | Fuelling Poverty |
Ishaya Bako tí a bí ní ọjọ́ ọjọ́gbọ̀n Oṣù kejìlá ọdún 1986 jẹ́ olùdarí fíímù Nàìj́iríà àti òǹkọ̀wé fíimù.[1]
Ìlú Kaduna ni wọ́n bí i, níbi tó ti gbé ní gbogbo ayé rẹ̀ tó sì tún padà lọ sí ìlú Lọ́ńdọ̀nù, níbi tó ti kàwé ní Ilé-ẹ̀kọ́ Fíìmù Lọ́ńdọ̀nù.
Lẹ́yìn tí ó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ Fíímù ti Ìlú Lọ́ńdọ̀nù, Bako tẹ̀síwájú sí ìwé àfọwọ́kọ àti ṣe ìdarí Awards Africa Movie Academy Awards (AMAA) tí ó gba Braids on a Bald Head. Ó jáwé olúborí fún Àwọn Ẹ̀bùn Fíímù Kúkúrú Tí ó dára jùlọ ní 8th Africa Movie Academy Awards. Ó jẹ́ ohùn tí ó ń yọjú tàbí dìde ní ti ìran rẹ̀ àti ọmọ ẹgbẹ́ kan tí a yàn èyiun Global Shapers, ìkójọpọ̀ àwọn aláfojúsùn ọ̀dọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ World Economic Forum.[2]
Fíìmù rẹ̀, Fueling Poverty, ìwé ìtàn lórí òsì àti owó-ìrànlọ́wọ́-lórí-epo ní Nàìjíríà, jẹ́ ohun tí onímọ̀-lítírésọ̀ Wọlé Ṣóyínká jẹ́ asọ̀tàn rẹ̀. Ó ń gbé ní olú-ìlú Nàìjíríà Abuja, FCT.[3] Fíìmù rẹ̀ The Royal Hibiscus Hotel ni a ṣe àfihàn ní 2017 Toronto International Film Festival.
Ó tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òǹkọ̀wé fún fíímù Lionheart (fíìmù ọdún 2018).[4]