Ìyípadà ojú-ọjọ́ ti yọrí sí ìgbọ́ná ní America pẹ̀lú 2.6°F (1.4°C) láti ọdún 1970. [2] Ojú-ọjọ́ ti America ń yípadà lọ́tà tó yàtọ̀ sí ti àwọn agbègbè rẹ̀.[3][4] Láti ọdún 2010 sí ọdún 2019 ni ìlú America ti ń ní àdojúkọ ìgbóná nínú ojú-ọjọ́.[5]
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojú-ọjọ́ tó ga jù, àwọn ẹranko tó ti ń lọ sóko ìgbàgbé, àgbàrá òjò àti ìyuàngbẹ-ilẹ̀ ń pọ̀ si.[6][7][8] Àwọn ìyípadà tó ń dé bá ojú-ọjọ́ ń kó ipa ribiribi lórí àwọn ìjì-líle àti ìpele òkun tó ń ga si, ó sì tún ń kan àwọn agbègbè nínú ìlú.
Ní àpapọ̀, láti ọdún 1850, orílẹ̀-èdè America ti tú èéfín gáàsì tó pọ̀ jù lọ, ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ń lo gáàsì, tó sì ń ní ìyípadà tó ń dé bá ojú-ọjọ́ wọn.[9][10]