Jemima Osunde | |
---|---|
Osunde appearing on an episode of NdaniTV's Real Talk | |
Ọjọ́ìbí | April 30 1996 (age 24) Lagos, Lagos State, Nigeria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Lagos |
Iṣẹ́ | |
Gbajúmọ̀ fún | Shuga |
Website | Official website |
Jemima Osunde tí wọ́n bí ní ọgbọ̀njọ́ oṣù Kẹrin ọdún 1996. [1] jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé , model àti olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán Ọmo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2] Ó di ìlú-mòọ́ká lẹ́yìn tí í ó kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn "Jemima" nínú eré àtìgbà-dégbà onípele ti Shuga.[3]Wọ́n yan Osunde fún amì-ẹ̀yẹ ti Best Actress in a Leading Role àyẹyẹ 15th Africa Movie Academy Awards ẹlẹ́kẹẹ̀ẹ́dógún irú rẹ̀ tí yóò wáyé fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré The Delivery Boy (2018).[4]
Wọ́n bí Osunde sí ìlú Edo, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa physiotherapy ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì Ìpínlẹ̀ Èkó.[5][6][7]Ó kópa nínú eré Jungle Jewel lẹ́yìn tí àbúrò bàbá rẹ̀ gbàá níyànjú láti máa lọ ṣeré ìtàgé.
Ó kópa bí ẹ̀dá-ìtàn "Laila" nínú eré àtìgbà-dégbà onípele ti MTV Shuga.Ó pa ìkópa tì nínú eré yí nígbà tí wọ́n gbé eré náà lọ sí orílẹ̀-èdè South Africa, àmọ́ ó tún bá wọn kópa padà nígba tí eré náà padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [8] Ní ọdún 2018, ó kópa nínú eré Rumour Has it pẹ̀lú òṣèré mìíràn bíi: Linda Ejiofor lórí NdaniTV's .[9][10]
Osunde tún báwọn kópa nínú ìpele keje lórí MTV Shuga lásìkò ìsémólé COVID-9 .[11][12].
Ní ọdún 2019, Osund jáde ẹ̀kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Yunifásitì Èkó nínú ìmọ̀ physiotherapy.[13]
|url-status=
ignored (help)
Wikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Jemima Osunde |