Jonis Bascir | |
---|---|
![]() | |
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kẹ̀sán 1960 Rome, Italy |
Iṣẹ́ | actor, musician |
Ìgbà iṣẹ́ | 1990s–present |
Olólùfẹ́ | Nicoletta |
Parent(s) | Haji Bashir Ismail Yusuf |
Website | jonis.it |
Jonis Bascir tí wọn bí ní ọjọ́ kẹtadínlógún oṣù Kẹsàn-án ọdún 1960, jẹ́ òṣeré àti àkòrin tí ọmọ orílẹ̀ ède Somalia àti Italy.
Jonis jẹ́ ọmọ Muheddin Hagi Bascir, a sì bi ní ìlú Rómù ní ọdún 1960.[1][2] Bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀ ède Somalia, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀ ède Italy.[1] Ó jẹ́ ọmọ-ọmọ Haji Bashir Ismail Yusuf, ààrẹ Somalia àkọ́kọ́.
Ọ̀pọ̀ mo Jonis fún ipa rẹ̀ nínú eré Un medico in famiglia (1998–2008), ọkàn lára àwọn eré oníṣe Rai 1.[1] Ara àwọn eré míràn tí ó ṣe ni The Stone Merchant (2006), Anita Garibaldi (2012) àti Regalo a sorpresa (2013).[5]
Òun ni agbenusọ̀rọ̀ fún Kosè coffee.[1]