Jadesola Osiberu | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹjọ 1985 |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Manchester Pan-Atlantic University |
Iṣẹ́ | Olùkọ̀tàn, Adarí eré àti Olùgbéré jáde |
Jadesola Osiberu jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó yan iṣẹ́ kíkọ ìtàn sinimá àgbéléwò, tí ó sì tún jẹ́ adarí eré orí-ìtàgé àti olùgbéré jáde láàyò.
Wọ́n bí Jádesọlá sí ìdílé Ọba tí bàbá rẹ̀ jẹ́ Adéwálé Òṣíbẹ̀rù ti Ìlú Ẹ̀Pẹ́ Ṣàgámù.[1] Jádesọlá bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kó oníwé mẹ́wàá rẹ̀ ní Ìlú Ìbàdàn ṣáájú kí ó tó gba oyè ìmọ̀ akọ́kọ́ nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ Kọmpútà láti ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Manchester.[2] Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Pan-Atlantic University, níbi tí ó ti kẹ́kọ́ nípa ìbánisọ̀rọ̀ [3]
Jádesọlá pinu láti tẹpá mọ́ iṣẹ́ gbígbé eré sinimá jáde, pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹ̀rọ kọmpútà tóẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè.[3] Ilé-iṣẹ́ Paulse fi orúkọ rẹ̀ sí ara àwọn obìnrin tí mẹ́wàá tí wọ́n ń kópa ribiribi nínú ìṣàpilẹ̀kọ eré sinimá ní ilẹ̀ Nàìjíríà láti fún wọn ní amì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá fún iṣẹ́ ribi ribi wọn.[4] Òṣíbẹ̀rù dá ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ Tribe85 production sílẹ̀ ní ọdún 2017, pẹ́lú èrò láti máa sọ àwọn ìtàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ fún gbogbo.aráyé gbọ́.[5] During an interview with BellaNaija, her work ethic, attention to detail and creative drive was praised by the interviewer.[6]
Ní ọdún 2018, òun ni ó ń lékè àtẹ àtòjọ Nollywood Film Festival ti orílẹ̀-èdè Scotland.[7]
Ní ọdún 2017, Ó kọ eré Isoken tí ó sì tún darí rẹ̀. Eré yí dá ló ìṣòro tí ó ń kojú àwọn wúndíá obìnrin tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí àti ìbáṣepọ̀ wọn ní ìwòye orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ adarí-eré tó peregedé jùlọ fún Africa Magic Viewers Choice Award tí wọ́n sì tún yàán fún Africa Movie Academy Award fir Best Director ní ọdún 2018.pẹ̀lú bí ó ṣe darí eré náà. [8] Oríṣiríṣi àríwísí ni ó ti wáyé.láti ọ̀dọ̀ àwọn.onímọ̀ lórí ipò tí àwọn obìnrin wà láwùjọ látàrí eré yí [9] àwọn tí wọ́n ń ṣe agbátẹrù Culture Custodian ni wọ́n ti ṣàlàyé bí eré tí Òṣíbẹ̀rù gbé jáde yí ṣe ṣe pàtàkì sí nípa kíkojú ìfẹnu ṣáátá àwọn obìnrin láwùjọ wa, pàá pàá jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[10]
Ni ó jẹ́ eré ti.àwọn ènìyàn.ń fojú sọ́nà fún láti láti ọwọ́ Jádesọlá Òṣíbẹ̀rù, ní èyí ti àwọn òṣèré bíi: Rita Dominic, Gideon Okeke àti Blossom Chukwujekwu.[7][11]
Jádesọlá ṣe ìgbéyàwó ní ọjọ́ kọkànlá oṣù Karùún ọdún 2019 ní Ìlú Ṣàgámù ní Ìpínlẹ̀ Ògùn .[12]