Mawlānā, Mufti Kafilur Rahman Nishat Usmāni | |
---|---|
![]() | |
Ọjọ́ìbí | 5 March 1942 Deoband,United Provinces (1937–50) |
Aláìsí | 1 August 2006 | (ọmọ ọdún 64)
Resting place | Qasmi cemetery |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Darul Uloom Deoband, Aligarh Muslim University |
Notable work | Urdu translation of Fatawa 'Alamgiri[1] |
Àwọn olùbátan | Usmani family of Deoband |
Kafīlur Rahmān Nishāt Usmānī (5 March 1942 – 1 August 2006) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè India, amòfin, àti akéwì tó jẹ́ Mufti ti Darul Uloom Deoband. Òun ni ọmọ-ọmọ Azizur Rahman Usmani. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Darul Uloom Deoband àti Aligarh Muslim University. Ó ṣe ògbufọ̀ Fatawa 'Alamgiri sí èdè Urdu, ó sí ṣe ìgbéjáde àwọn ìlànà ẹ̀sìn tó ju bí i ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lọ[2][3].
A bí Kafīlur Rahmān Nishāt Usmānī sínú ìdílé Usmani family of Deoband ní ọjọ́ kẹta, ọdún 1942.[4] Bàbá rẹ̀ ni Jalilur Rahmān Usmānī, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Azizur Rahman Usmani àti olùkọ́ "tajwid" àti"qirat" ní Darul Uloom Deoband.[5]
Usmānī kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Darul Uloom Deoband ní ọdún 1961, ó sì gboyè M.A nínú èdè Lárúbáwá ní Aligarh Muslim University ní ọdún 1975.[4] Àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni Syed Fakhruddin Ahmad àti Muhammad Tayyib Qasmi.[5] Ní ọdún 139, wọ́n yan Usmāni sípò Mufti ní Darul Uloom Deoband.[6] Ó wà nípò náà fún ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, nígbà yìí gan-an ni ó ṣe ìgbéjáde àwọn ìlànà ẹ̀sìn tó ju bí i ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lọ.[7] Ó tún jẹ́ akéwì, ó sì kọ àwọn ewì bíi: ghazal, hamd, naat, nazm, marsiya, àti qasīda, tí ó jẹ́ ewì Urdu.[8]
Usmānī kú ní ọjọ́ kìíní, oṣù kẹjọ, ọdún 2006, wọ́ sì sin ín sí ìtẹ́ ìsìnkú Qasmi, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìté òkú bàba-bàbá rẹ̀, Azizur Rahman Usmani.[9] Ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Fuzailur Rahman Hilal Usmani ni ó darí àdúrà ètò ìsìnkú rẹ̀.[9]
Usmānī kọ àwọn ìwé bíi: Shanāsa, Ziyārat-e-Quboor, Hayāt Ibn Abbās, Hayāt Salmān Fārsi, Hayāt Abu Hurairah, Sirāj al-Īdāh (èyí tó jé àsọyé fún Hasan Shurunbulali's Nur ul Idāh) àti Ā'īna-e-Bid'at.[10]
Usmānī ṣe ògbufọ̀ àti àlàyé àwọn ìwé lórí "dars-e-nizami" láti èdè Lárúbáwá àti Persia sí èdè Urdu.[7] Àwọn ìwé láti èdè Lárúbáwá sí èdè Urdu ni: Sirāj al-Ma'āni, Sirāj al-Wiqāya (ògbufọ̀ sí Urdu àti àsọyé fún Sharh-ul-Wiqāya), Sirāj al-Matālib, Tafhīm al-Muslim (ògbufọ̀ sí Urdu àti àsọyé fún Fath al-Mulhim tí Shabbir Ahmad Usmani kọ), àti Fatawa 'Alamgiri.[11] Àwọn ìwé láti èdè Persia sí Urdu ni: Gulzār-e-Dabistān, Tuhfat al-Muwahhidīn, Masā'il Arba'īn, àti Rubāʿiyāt tí Baha' al-Din Naqshband kọ.[11]