Kemi Adetiba

Kemi Adetiba
Ọjọ́ ìbí(1980-01-08)8 Oṣù Kínní 1980
Lagos, Lagos State, Nigeria
Iṣẹ́Filmmaker, music video and television director

Kemi Adetiba jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó sì jẹ́ olùdarí fídíò orin lóríṣiríṣi, aṣẹfíìmù àgbéléwò àti olùdarí ètò lórí tẹlifíṣọ́ọ̀nù tí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ti hàn lórí Channel O, MTV Base , Soundcity TV, BET àti Netflix .[1][2]

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọjọ́ kẹjọ oṣù kìíní ọdún 1980 ni a bí Kemi ní ìpínlẹ̀ Èkó,[3] Ìyá rẹ̀ ni Mayen Adetiba tí ó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ àti òṣèré. Kemi Adetiba bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ sínú ètò orí afẹ́fẹ́ nígbà tí wọ́n fi ṣe ìpolówó ọṣẹ OMO. Èyí sì hàn pé ipa ẹsẹ̀ bàbá rẹ̀ Délé Adetiba ló ń tọ̀.[4]

Kemi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi agbétò sórí rédíò pẹ̀lú Rhythm 93.7 FM, níbi tí ó ti ǹ darí ètò méjì kan tí ń jẹ́ "Soul’d Out" àti "Sunday at the Seaside". Kemi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi àtúnkọ orin sí orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá bíi Spotify àti SoundCloud láìfi orúkọ ara rẹ̀ síbẹ̀ àmọ́ ó ń lo orúkọ kan tí ń jẹ́ 'hule'.

Kemi Adetiba yí kúrò láti agbétò sórí rédíò sí agbétò sórí tẹlifíṣọ́ọ̀nù. Ó ń gbé àwọn ètò bíi Studio 53, Temptation Nigeria pẹ̀lú Ikponmwosa Osakioduwa lórí Mnet. Ó tún dárí ètò Maltina Dance All fún sáà mẹ́ta.[5]

Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta pẹ̀lú àṣeyọrí nínú iṣẹ́ rẹ̀, Kemi forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú New York Film Academy láti kọ́ nípa àwọn ohun àmúyẹ fún àwọn tó ń darí fíìmù. Lónìí, Kemi sì ti di ògbóǹtarìgì olùdarí fíìmù àgbéléwò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Áfíríkà. Fíìmù ìṣẹ́jú díẹ̀ tí Kemi Adetiba ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Across a Bloodied Ocean ni àjọ Pan African Film Festival and National Black Arts Festival ṣe lámèétọ́ ẹ̀.[6]

Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹsàn-án ọdún 2016, Kemi Adetiba kópa nínú fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Wedding Party".

Ní ọdún 2017, ó jẹ́ olùdarí ètò kan lórí tẹlifíṣọ́ọ̀nù tí ń jẹ́ "King Women" níbi tí ó ti gbé ìyá rẹ̀ Mayen Adetiba sórí afẹ́fẹ́. Àwọn obìnrin mìíràn tí ó pè wá sórí ètò "King Women" náà ni Chigul, Taiwo Ajai-Lycett, TY Bello and Tara Durotoye.[7]

Ààtò àwọn àmì ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Díẹ̀ lára àwọn àmì ẹ̀yẹ tí iṣẹ́ rẹ̀ ti bí ni fídíò obìnrin tí ó dára jù lọ fún orin "Ekundayo" láti owó TY BelloSoundcity TV Music Video Awards, fídíò obìnrin tí ó dára jù lọ fún orin "Today na Today" láti owó Omawunmi2010 Nigeria Entertainment Awards. Àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ni "onye" tí Waje kọ pẹ̀lú Tiwa Savage, "Anifowose" tí Olamide kọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

A yan Kemi gẹ́gẹ́ bíi olùdaríbìnrin tí ń gbé fídíò orin jáde tí ó dára jù lọ niThe Headies 2014 ní ọdún 2014.[8] Ó gboyè City People Entertainment Award fún olùdarí fídíò orin tí ó dára jù lọ ní ọdún 2015[9] àti àmì ẹ̀yẹ HNWOTY tó jẹ́ àmì ẹ̀yẹ ọdọọdún fún obìnrin tó dára jù lọ nínú fíìmù àti tẹlifíṣọ́ọ̀nù ní ọdún 2017.[10]

Àwọn Fíìmù tó ti dárí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn fídíò orin tó ti dárí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Being only female director? No big deal". Vanguard News. 
  2. "Kemi Adetiba: Sworn To Defend All Visual Images - Nigerian News from Leadership Newspapers". Nigerian News from Leadership Newspapers. 
  3. "Kemi Adetiba Gets Really Naughty For Her 34th Birthday [PHOTOS] | Nigerian Entertainment Today - Nigeria's Number 1 Entertainment Daily". Nigerian Entertainment Today - Nigeria's Number 1 Entertainment Daily. 2014-01-12. Archived from the original on 3 December 2017. Retrieved 2016-05-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Okafor, Onnaedo. "Kemi Adetiba: 6 Things You Didn't Know About Nigeria's 'Bruce Lee of Visuals'". pulse.ng. Archived from the original on 11 August 2017. Retrieved 2016-05-13. 
  5. Pulse (11 April 2012). "Media Personality, Kemi Adetiba- "I Have Been Blessed!!!"". Archived from the original on 12 October 2014. Retrieved 25 April 2020. 
  6. "Happenings - CELEB OF THE WEEK: Kemi Adetiba, Taking The Media By Storm". Archived from the original on 12 October 2014. Retrieved 25 April 2020. 
  7. "Mayen Adetiba speaks on how she dealt with patriarchy at work on the latest episode of King Women". ID Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-06-28. Archived from the original on 7 March 2022. Retrieved 2020-04-24. 
  8. Editor. "Kemi Adetiba honoured by Headies and BenTv Nominations". Nigerian Entertainment Today - Nigeria's Number 1 Entertainment Daily. Archived from the original on 2 December 2016. Retrieved 7 October 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "Kemi Adetiba bags best music video director City People Entertainment Awards - Entertainment afriqueEntertainment afrique". Entertainment afrique (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-08-17. Archived from the original on 5 March 2017. Retrieved 2016-05-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. "Kemi Adetiba Remains Thankful As She Bags Her Latest Achievement". Fab Woman Ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-11-12. Retrieved 2017-12-11. 
  11. "Nigerians react to Kemi adetibas new project KING WOMAN". 
  12. "New Video: Lynxxx & Stephanie Coker In "My Place"". Channels Television. 
  13. "Niyola goes topless for new video". 
  14. "Olamide "Baddo" Drops Hot New Videos - Channels Television". Channels Television. 
  15. "Waje Release "Onye" Video Featuring Tiwa Savage". Channels Television. 
  16. "Niyola releases new video". 
  17. "Bez Drops New Video, Say". Channels Television.