Kiki Omeili | |
---|---|
Kiki Omeili | |
Ọjọ́ìbí | Nkiruka 'Kiki' Omeili May 31st, 1981 Lagos, Lagos State, Nigeria |
Iṣẹ́ | Actress, presenter, doctor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2011 – present |
Nkiruka Kiki Omeili jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ fún ipa Lovette[1] tí ó kó nínú eré Lekki Wives. [2] Àwọn ẹ̀yán tún mo fún ipa Blessing tí ó kó nínú eré Gbomo Gbomo Express ni ọdún 2015.
Wọ́n bí Omeili sì ìlú Èkó ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó sì jẹ ọmọ ìkejì láàrin àwọn ọmọ mẹrin tí àwọn òbí rẹ bí. Ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà igbo ni ìpínlè Anambra. Bàbá rẹ̀, Charles ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé ifowopamo tí First Bank Nigeria. Ìyá rẹ̀, Maureen ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí aṣọ́bodè fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n ni ìlú Ibadan.
Ó gboyè nínú ìmò ìlera láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Lagos.[3]
Ní ọdún 2011, Omeli kò ipa Debbie nínú eré Behind the smile. Ní ọdún 2012, ó kopa ninu eré Married But living single, pẹ̀lú àwọn gbajúmọ̀ òṣèré bíi Funke Akindele, Joseph Benjamin, Femi Brainard àti Joke Silva.[4]
Ní ọdún 2011, Omeili ṣe atọkun fún ètò ìjọ Dance 243.[5] Ni ọdún 2016, ó ṣe ère ranpe tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Unprotected. Omeili tí kópa nínú àwọn eré bíi Footprints, The Valley Between[6], Gidi Culture ati bee bee lo.