Kọ́lá Túbọ̀sún | |
---|---|
![]() | |
Ọjọ́ìbí | Kọ́láwọlé Olúgbémiró Ọlátúbọ̀sún (Ọ̀ládàpọ̀) 22 Oṣù Kẹ̀sán 1981 Ibàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Orúkọ míràn | Kọ́lá Ọlátúbọ̀sún |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan, Moi University, Southern Illinois University Edwardsville |
Iṣẹ́ | Akọ́mọlédè, Oǹkòwé, Olùkó |
Ọmọ ìlú | Ibàdàn |
Alábàálòpọ̀ | Temie Gíwá |
Parent(s) | Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀ |
Website | ktravula.com |
Kọ́lá Túbọ̀sún jẹ́ akọ́mọlédè, oǹkọ̀wé, ọ̀mọ̀wé ati olùgbásàga ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà [1][2][3] tí iṣẹ́ ipa rẹ̀ ti gbajúmọ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ka èkọ́, ìmọ̀-ẹ̀rọ, lítírésọ̀, ìròyìn, ati ẹ̀ka akọ́mọlédè. O jẹ́ aṣojú àṣà ni (Southern Illinois University Edwardsville, 2009), Ó ti gba àkànṣe àmì-é̀yẹ Premio Ostana fuń litireṣọ̀ èdè abínibí lọ́dún.[4][5][6] Ó jẹ́ oǹkọ̀wé èdè Yorùbá àti Gèésì.
A bí Tubosun ní ìlú Ibadan, Nàìjíríà ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1981. Ó ní àmì ẹyẹ Masters nínú ìmọ̀ Linguistics ní Southern Illinois University Edwardsville (ọdún 2012) àti àmì ẹyẹ BA ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn (ọdún 2005). Ó tún kàwé fún ìgbà díẹ̀ ní Yunifásitì Moi, Eldoret, Kenya ní oṣù kẹrin ọdún 2005.
With the help of volunteers and crowdsourcing contributors, he is creating an online compendium of Yoruba names with meanings and aural pronunciations.