Koseegbe | |
---|---|
Fáìlì:Koseegbe poster.jpeg | |
Adarí | Tunde Kelani |
Olùgbékalẹ̀ | Tunde Kelani |
Òǹkọ̀wé | Akinwunmi Isola |
Àwọn òṣèré | Kola Oyewo Wole Ameleo Jide Kosokoo Toyin A Babatope |
Olóòtú | Idowu Nubi |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Mainframe Films and Television Productions |
Olùpín | Alasco Video Film Production Blessed J.O. Adeoye Alelele Bros. & Co |
Déètì àgbéjáde | 1995 |
Àkókò | 102 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | Yoruba Language |
Kòseégbé jẹ́ fíìmù Yorùbá ti ọdún 1995, tí Tunde Kelani darí. Fíìmù yilí dá lórí eré orí-ìtàgé kan tí Akínwùmí Iṣọ̀lá ṣe. Àwọn akópa náà jẹ́ òṣèré láti tíátà Obafemi Awolowo University.[1] Wọ́n ṣàgbéjáde rẹ̀ láti ọwọ́ Mainframe Films and Television Productions.[2]
Koseegbe jẹ́ ìtàn tó dá lórí òṣìṣẹ́ kọ́sítọ́ọ̀mù kan tó ń hùwà tó tọ́. Òṣìṣẹ́ yìí ni wọ́n fi rọ́pọ̀ ọ̀gá kan tó ń hùwá̀ ìbàjẹ́, tí wọ́n sì lé lọ. Ní ibi iṣẹ́ tuntun rẹ̀, ó gbìyànjú láti tún ibiṣẹ́ náà ṣe àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó kéré níbẹ̀ ò gbà fún un. Nínú ìgbìyànjú wọn láti le kúrò ní ibiṣẹ́, wọ́n fi ẹ̀sùn burúkú kan kàn án. Ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó borí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe fún ìparun rẹ̀.[3][4]
Koseegbe jẹ́ fíìmù ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Tunde Kelani á ṣe, ó sì jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ pẹ̀lú Akínwùmí Iṣọ̀lá. Ó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i eré orí-ìtàgé, pẹ̀lú àkólé kan náà láti ọwọ́ Isola. Wọn ò rí àkọsílẹ̀ fún fíìmù náà ní ìgbà yẹn. Kelani ló ṣẹ̀ wá fún wọn ní Driving Miss Daisy láti fi ṣe àtẹ̀gùn.[5] Wọ́n gbe jáde ní ọdún 1995.[6]
Wọ́n sì tò ó pọ̀ mọ́ ọ̀kan lára àwọn fíìmù Yorùbá mẹ́wàá tó tà jù lọ ní lásìkò náà.[7]
<ref>
tag; no text was provided for refs named :02