Lateef Adedimeji | |
---|---|
Adedimeji at AMAA 2021 | |
Ìbí | 1 Oṣù Kejì 1984 Isolo, Lagos State, Nigeria |
Iṣẹ́ |
|
(Àwọn) ìyàwó | Oyebade Adebimpe (m. 2021) |
Adetola Abdullateef Adedimeji Listen (wọ́n bí i ní February 1, 1984) ó jẹ́ ọmọ orílẹ́-èdè Nigerian òṣèré àti Agbéréjáde. [1][2] Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n mọ̀ ọ́n fún ipa gbòógì rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó kó nínú eré Yéwándé (Yewande Adekoya)'s ní ọdún 2013 èyí tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní Kudi Klepto bẹ́ẹ̀ ni ó ti kó ipa takuntakun nínú àwọn eré tí wọ́n lé ní ọgọ́rùn-ún (100) [3] Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ipa nínú eré orí ìtàgé àti àgbéléwò láti bí ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Òun ni ó jẹ́ aṣojú ìpolówó brand ambassador fún ilé iṣẹ́ Airtel àti Numatville Megacity.[4]
Wọ́n bí Lateef Adedimeji ní ọjọ́ kì-ín-ní, oṣù kejì, ọdún 1984 ni agbegbe kan tí wọ́n ń pè ní Isolo, Lagos State. Ó jẹ́ ọmọ Abeokuta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn Ogun State.[5]
Lateef bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Ire Akari Primary School, Isolo, Lagos State, bẹ́ẹ̀ ni ó lọ sí Ilamoye Grammar School Okota ní Ìpínlẹ̀ Èkó Lagos State fún ètò ẹ̀kọ́ girama. [1] Bẹ́ẹ̀ ni ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Onikan tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó Lagos State níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣeré orí ìtàgé. [1] Ẹ̀bùn ìkọ̀wé rẹ̀ àti bí a ṣe ń ṣeré orí ìtàgé gbèrú si lábẹ́ àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba Non-governmental organization (NGO) èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ (Community Life Project). [1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ Olabisi Onabanjo University, níbi tí ó ti gba oyè ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ bachelor's degree nínú Mass Communication.[6]
Lateef Adedimeji bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa lórí ìtàgé láti ọdún 2007, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ijó jíjó, [1] tí ó sì tún lọ ilé ẹ̀kọ́ tí a ti ń kọ́ nípa ijó jíjó. Ó jẹ́ òṣèré Actor tí ó ti kó ipa onírúurú lórí ìtàgé láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ṣùgbọ́n tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré ní ọdún 2007 nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ Orisun TV. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi atọ́kùn ètò ní ilé iṣẹ́ agbóhùngbójìjí ti Orísun TV, orúkọ ètò tí ó máa ń ṣe nípa à ń ṣe eré orí ìtàgé ni Sábàbí. Ní ìgbà tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ gírámà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti ń ṣe eré orí ìtàgé, àwọn àjọ kan tí wọn kì í ṣe ti ìjọba yàn án gẹ́gẹ́ bíi aṣojú àti olúdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àìsàn kògbóògùn HIV/AIDS èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń kó láti ara ìbálòpọ̀ akọ sí abo lọ́nà tí kò ní ìdáàbò bò. Iṣẹ́ Lateef Adedimeji ni láti kó ipa nínú eré tí ó máa dá àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn ààrùn tí a le kó láti ara ìbálòpọ̀, àwọn ewu tó wà nínú kí á má tọ́jú ààrùn náà àti bí wọ́n ṣe le di ààrùn kògbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni ó tún kópa nínú jíjẹ́ kí àwọn ènìyàn ó mọn ẹ̀tọ́ àti ojúṣe wọn lábẹ́ òfin. Lateef jẹ́ ẹnìkan tí ó tètè ṣe àwárí ara rẹ̀ nínú kíkópa nínú eré orí ìtàgé tí ó sì gbé ìgbésẹ̀ láti wọ ẹgbẹ́ àwọn òǹṣèré. Ó ti kó ipa onírúurú bẹ́ẹ̀ ni ó ti bá àwọn òṣèré jàǹkànjàǹkàn ṣe eré àgbéléwò papọ̀ láti ìgbà tí ó ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré tíátà. Ọ̀pọ̀ ni ó mọ̀ ọ́n fún ipa tí ó máa ń kó gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí omi ẹkún kò jìnnà sí lójú. Ní ọdún 2016, ó gba àmì ẹ̀yẹ 2016 Best of Nollywood Awards fún òṣèré tí ó léwájú jùlọ nínú eré Yorùbá. [7] In 2015, he was nominated for City People Entertainment Awards for the 2015 Most Promising Actor of the year. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn a tilẹ̀ máa ń pè é ní àbúrò òṣèré kùnrin n nì ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọ̀dúnladé Adékọ́lá ṣùgbọ́n èyí tí kò rí bẹ̀. Ẹ̀bùn ìkọ̀wé tí ó ní ti mú un bá àjọ àgbáyé UNICEF dá iṣẹ́ papọ̀ rí. [8] He was awarded the face of Nollywood male[9] during the ENigeria Newspaper Night of Honour on 30 October 2021.
Ní ọjọ́ kejìdínlógún, 18 December 2021, Adedimeji gbé akẹgbẹ́ rẹ̀ níyàwó, ẹni tí òun náà jẹ́ òṣèré eré orí ìtàgé, Oyebade Adebimpe pẹ̀lú ìgbéyàwó alárinrin. [10][11]
Year | Award ceremony | Prize | Result | Ref |
---|---|---|---|---|
2014 | Odua Movie Awards | Best Actor | Gbàá | [18] |
2015 | Gbàá | |||
Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
City People Entertainment Awards | Most Promising Actor of the Year (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
2016 | Best Supporting Actor Of The Year (Yoruba) | Gbàá | ||
Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
2018 | Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Gbàá | [19] |
City People Movie Awards | Best Actor Of The Year (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
2019 | Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Wọ́n pèé | [20] |
Best Supporting Actor (Yoruba) | Gbàá | |||
2020 | 2020 Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead role –Yoruba | Wọ́n pèé | [21] |
2021 | Africa Movie Academy Awards | Best Actor in a Leading Role | Wọ́n pèé | [22] |
2022 | Hollywood and African Prestigious Awards (HAPA Awards) | Best Actor in Africa | Gbàá | [23] |
<ref>
tag; no text was provided for refs named theinfopro.com.ng