Living in Bondage | |
---|---|
Fáìlì:Living in Bondage 1992.jpg | |
Adarí | Chris Obi Rapu |
Olùgbékalẹ̀ | Ken Nnebue |
Òǹkọ̀wé | Kenneth Nnebue Okechukwu Ogunjiofor |
Àwọn òṣèré | Kenneth Okonkwo Nnenna Nwabueze Okechukwu Ogunjiofor Francis Agu Bob-Manuel Udokwu |
Déètì àgbéjáde |
|
Àkókò | 163 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | Igbo |
Living in Bondage (Gbígbé nínú Ìgbèkùn), Apá kìn-ín-ní àti Apá kejì jẹ́ eré àgbéléwò asaragágá orílẹ èdè Nàìjíríà tí Chris Obi Rapu jẹ́ Olùdarí rẹ̀, a sì ti ọwọ́ Kenneth Nnebue àti Okechukwu Ogunjiofor,[1] kọ ọ́. Aṣagbátẹrù erè yìí ni Ogunjiofor, Jafac Wine ló ṣe onígbọ̀wọ́ eré náà. Lára àwọn Akópa inú eré-oníṣe àgbéléwò,[2] yìí ni Kenneth Okonkwo àti Nnenna Nwabueze nínú ẹ̀dá-ìtàn àlàjá wọn. Ó jẹ́ eré-oníṣe àgbéléwò orílẹ -èdè Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí ó dé ipile àṣeyọrí tó ní iyì nínú.[3]
Ní Oṣù Kẹjọ ní ọdún 2015,Charles Okpaleke gba ẹ̀tọ́ lórí Living in Bondage fún àkókò ọdún mẹ́wàá lábé ìṣàkóso ilé-isẹ́ ìsagbátẹrù Play Entertainment Network.[4] Ní oṣù kọkànlá ọdún 2019, A fi Eré-oníṣe Àgbéléwò ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lẹ́ tí gbogbo tí tomodé-tàgbá tí ń ṣàfẹ́rí Living in Bondage: Breaking free,[5][6] hàn, fún ìgbà Àkọ́kọ́ ni ìlú Eko.[7]
Andy Okeke (Kenneth Okonkwo) àti ìyàwó rẹ̀ Merit (Nnenna Nwabueze) bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìjákunlẹ̀ pàdé – bí ìṣe ṣe ń bọ́ lọ́wọ́ wọn, ni wọ́n tún yan ara wọn jẹ nípa ṣíṣe Àgbèrè, wọn pàdánù owó Ìfipamọ́ wọn nínú Ìdókòwó ńlá. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọkùnrin wọ̀bìà àti onífẹ̀ẹ́-kú-fẹ̀ẹ́ ló máa kọnu ìfẹ́ sí Merit, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀gá rẹ̀ Ichie Million (Francis Agu) àti Chief Omego (Kanayo O. Kanayo). Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, Andy máa ń sábà ṣe àfiwéra àìlóríre ti rẹ̀ pẹ̀lú Àṣeyọrí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pàápàá Paul (Okechukwu Ogunjiofor) tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́ rẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo àtìlẹ́yìn àti sùúrù tí Merit ní, Andy ń wá gbogbo ọ̀nà láti dí olówó pẹ̀lú ohunkóhun àti ọ̀nàkọnà tí ó bá fẹ́ gbà. Pọ́ọ̀lù ọlọ́gbọ́n Àrékérekè tú àṣírí rẹ̀ - Ẹgbẹ́ òkùnkùn tí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ máa ń dá májẹ̀mú Ìsòótọ́ àti ìdúróṣinṣin pẹ̀lú Lucifer, tí wọ́n sì tún máa ń pá àwọn tí wọ́n fẹ́ràn gẹ́gẹ́ bí ohun ètùtù láti rí ọrọ̀ àti owó jaburata. Láì fi àkókò ṣòfò Andy gbà láti fi ìyàwó rẹ̀ Merit ṣe ìrúbọ ètùtù. Merit kú sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn ọjọ́ tí wọ́n ṣe ètùtù kí ó tó kú ó fi ọkọ rẹ̀ ré.
Ọrọ̀ pàjáwìrì àti ìgbéyàwó ẹlẹ́kejì tí Andy ní fa Àkíyèsí àwọn àna rẹ̀ àná, èyí tí ó mú kí wọ́n fi ẹ̀sùn pípa ọmọ wọn Merit kàn án. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní àwọn ìdojúkọ- bí àwọn ayàwòrán gbajúmò ṣe máa ń dá sí ìgbé sí ayé ojoojúmọ́ rẹ̀, ìyàwó tuntun rẹ̀ Ego (Ngozi Nwosu) gbé owó rẹ̀ sàlo lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, àti bí ẹ̀mí òkú Merit ṣé ń lé e kiri tí ó ṣì ń seru bà á ní àwọn ìgbà tí kò lérò. Andy tẹ̀síwájú láti máa bá Chinyere (Jennifer Okere) gbé gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, obìnrin míràn tí ọ̀rẹ́ Merit Caro (Ngozi Nwaneto), mú u pàdé. Chinyere kú ikú àìtọ́jọ́ lẹ́yìn ìgbà tí Caro fún ní májèlé jẹ. Lẹ́yìn èyí Caro gbìyànjú láti sá lọ sí òkè òkun pẹ̀lú owó tí Chinyere jí lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀. Caro kú nígbà tí ó ń lọ sí ilé ọkọ̀-òfuurufú lẹ́yìn ìgbà tí awakọ̀ kán gba lóju títì. Àwọn apànìyàn pa Paul lẹ́yìn tí Andy dalẹ́bi fún ìdí tí ó fi wọ́ inú ẹgbẹ́ òkùnkùn.
Lẹ́yìn gbogbo èyí, Andy padà lọ bèrè ìrànwọ́ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn náà, ṣùgbọ́n olúwo ẹgbẹ́ náà ní dandan ni ki ó pẹ̀rọ̀ fún òkú ìyàwó nípa gígé nǹkan ọmọ ọkùnrin rẹ̀ àti fífọ́ ara rẹ lójú. Ó kọ̀, ó sì di erè tí ó ń gbé lábẹ́ afárá di ìgbà tí Tina (Rita Nzelu)- ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ Aṣẹ́wó tẹ́lẹ̀ nígbà tí Andy kọ́kọ́ pàdé rẹ̀ tí ó mú lọ sí ẹgbẹ́ òkùnkùn wọn gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ètùtù kí àṣírí rẹ̀ tó tú , mú u lọ sí ilé-ìjọsìn níbi tí Andy tí jẹ́wọ́ wí pé òun lòún pá Merit, ìyá Andy (Grace Ayozie) sunkún létí ibojì ìyàwó ọmọ rẹ̀ ó sì tọrọ ìdáríjì.
Ní ìgbẹ̀yìn eré, Andy tí gba ìwòsàn, ó sì ń jọ́sìn pẹ̀lú àwọn ajíhìnrere onígbàgbó, tí wọ́n dáa lójú wí pé ó ti gba ìdáríjì fún gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ̀.[8][9][10]
Ní ọdún 2015, àwọn àgbà Òṣèré Ramsey Nouah àti Charles Okpaleke gba ẹ̀tọ́ lórí Living in Bondage láti ọwọ́ Kenneth Nnebue àtúnṣe eré náà ni ilẹ̀ Europe, America àti Nàìjíríà. Ìròyìn jáde lórí instagram ṣùgbọ́n ipele ìdàgbàsókè ló wà fún àkókò ọdún mẹ́ta.
Ní 2018, Nouah ṣe ìkéde pé àtúnṣe eré náà yóò wáyé ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lẹ́ èyí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Living in Bondage: Breaking Free, èyí tí ó jáde ní November 8, 2019. Nouah tí ó ṣe olúwo tuntun ṣé ìfarahàn àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bíi Olùdarí eré náà pẹ̀lú àwọn Òṣèré míràn tí wọ́n kópa nínú eré náà nígbà àkọ́kọ́ tí a gbé e jáde bíi Okonkwo, Udokwu, àti Kanayo. Ìtàn èyí dá lórí ọmọ Andy Nnamdi àti bí ó ṣe fi ìwà burúkú jọ bàbà rẹ̀. MBGN àná Muna Abii ṣé ìfarahàn àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí osere pẹ̀lú Swanky JKA tí ó ṣe ìpadàbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Òṣèré nínú eré yìí.
Ní Oṣù karùn-ún, ọdún 2020, á gbé fíìmù Àgbéléwò yìí sórí Netflix.