Liz Da-Silva | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Elizabeth Omowunmi Tekovi Da-Silva 10 Oṣù Kàrún 1978 Obalende, Ipinlẹ Eko |
Orílẹ̀-èdè | Togo ati Naijiria |
Iṣẹ́ | Osere |
Ìgbà iṣẹ́ | 2004–Iwoyi |
Àwọn ọmọ | 1 |
Elizabeth Ọmọ́wùnmí Tekovi Da-Silva (tí a bí ní Oṣù Kẹẹ̀fà Ọjọ́ 10, Ọdún 1978) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Tógò tí ó maá n sábà kópa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nínu fíìmù Yorùbá ti Nàìjíríà. Ní ọdún 2016, wọ́n yan Da-Silva fún àmì ẹ̀yẹ City People Movie Award fún ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tó dára jùlọ (ẹ̀ka ti eré Yorùbá) níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards.[1] Ní ọdún 2018 bákan náà, ó gba àmì ẹ̀yẹ fún òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Best of Nollywood Awards.[2]
A bí Da-Silva sí ọwọ́ àwọn òbí tí n ṣe ará Tógò ṣùgbọ́n tí wọ́n n gbé ní Nàìjíríà. A bi ní agbègbè tí a mọ̀ sí Obálendé ní Ìpínlẹ̀ Èkó níbití àwọn òbi rẹ̀ gbé, níbẹ̀ ló sì ti lo ìgbà èwe rẹ̀. Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú àwọn oniròyìn kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó ṣàlàyé pé Ìlú Èkó dà gẹ́gẹ́ bi ilé òun, ó sì sọ nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà pé òún wá láti ilé olórogún.[3] Da-Silva lọ sí Ireti Grammar School fún ètò-ẹ̀kọ́ ìwé mẹ̀wá rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Èkó níbi tó ti gba oyè-ẹ̀kọ́ B.Sc.[1][4]
Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan Da-Silva ṣàlàyé pé òún bẹ̀rẹ̀ sí nìfẹ́ sí láti darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ fíìmù ti Yorùbá ti Nàìjíríà ní àkókò tí òún wà ní ilé-ìwe girama. Nígbà náà lòwún bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínu àwọn eré ti ilé-ìwé. Da-Silva nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú àwọn oniròyìn The Punch ṣàlàyé pé òún kó ipa àkọ́kọ́ ní ilé-iṣẹ́ fíìmù Yorùbá ti Nàìjíríà ní ọdún 2004 nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Ìyábọ̀ Òjó.[5] Da-Silva di gbajúmọ̀ òṣèrè lẹ́hìn tí ó kó àwọn ipa gbòógì nínu fíìmù méj̀i kan; àkọ́lé àkọ́kọ́ ni Wákàtí Méta látọwọ́ Wale Lawal àti fíìmù kan ta pe àkọ́lé rẹ̀ ní Omidan látọwọ́ Ìyáboọ̀ Òjó.[6][3]
Da-Silva ní ọdún 2012 ṣe àkọ́kọ́ ìgbéréjáde rẹ̀ pẹ̀lu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mama Insurance, èyítí ó ṣe ìfihàn Ayò Mógàjí, Lánre Hassan,Ìyábọ̀ Òjó, Rónkẹ́ Òjó, àti Doris Simeon .[7][8]
Da-Silva jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ bíbí àti ọmọ orílẹ̀-èdè Tógò nípasẹ̀ àwọn òbi rẹ̀. Da-Silva ti ṣàlàyé Ìpínlẹ̀ Èkó bí ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sì ní àdìsọ́kàn láti ní ìṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní Tógò. Da-Silva Ní ọdún 2013 yípadà láti Krìstẹ́nì sí Islam.[8][9][10]
Year | Award | Category | Result | Ref |
---|---|---|---|---|
2018 | City People Entertainment Awards | Best Supporting Actress of the Year (Yoruba) | Wọ́n pèé | |
Best of Nollywood Awards | Best Supporting Actress –Yoruba | Gbàá |
Da-Silva lórúkọ, Bukky Wright gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe rẹ̀ nínú ilé iṣẹ́ fíìmù Yorùbá ní Nàìjíríà ó sì sọ pé òun ti nípa lórí, ọ̀nà ìṣèré rẹ̀ ní pàtàkì. [12]
<ref>
tag; no text was provided for refs named :22"